Wọ́n maa ṣírò ijanba ti wọn ṣe fun ẹ, ati bi wọn ṣe yapa àṣẹ rẹ, ati irọ́ ti wọn pa fun ẹ, ati ìyà ti o fi jẹ wọn

Wọ́n maa ṣírò ijanba ti wọn ṣe fun ẹ, ati bi wọn ṣe yapa àṣẹ rẹ, ati irọ́ ti wọn pa fun ẹ, ati ìyà ti o fi jẹ wọn

Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- pé: Arákùnrin kan jókòó níwájú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o wa sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo ni àwọn ẹrú kan ti wọn maa n pa irọ́ fun mi, wọn tun maa n janba mi, wọn si tun maa n yapa àṣẹ mi, mo maa n bú wọn, mo si maa n lù wọ́n, báwo ni ọ̀rọ̀ mi ati wọn ṣe maa jẹ ni ọdọ Ọlọhun? O sọ pe: “Wọ́n maa ṣírò ijanba ti wọn ṣe fun ẹ, ati bi wọn ṣe yapa àṣẹ rẹ, ati irọ́ ti wọn pa fun ẹ, ati ìyà ti o fi jẹ wọn, tí ìyà ti o fi jẹ wọn ba jẹ odiwọn ẹṣẹ wọn, a jẹ pe o ti ṣe déédéé ara wọn, o o nii ni ẹsan, o o si nii jẹ ìyà, ṣùgbọ́n ti iya ti o fi jẹ wọn ba kere si ẹṣẹ wọn, ìyẹn maa jẹ alekun fun ẹ, ṣùgbọ́n ti iya ti o fi jẹ wọn ba ju ẹṣẹ wọn lọ, wọn maa gba ẹ̀san alekun naa lara rẹ fun wọn”, o sọ pe: Ni arákùnrin naa wa rìn jìnnà, ni o ba bẹ̀rẹ̀ si nii sunkún ti o si n pariwo, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Ṣe o o ka tira Ọlọhun ti o sọ pe: {A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan}, aaya”, ni arákùnrin naa wa sọ pé: Mo fi Ọlọhun bura irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mi o ri ohun ti o loore fun emi ati awọn ju ki a pínyà lọ, mo n fi ọ jẹ́rìí pe gbogbo wọn ti di olómìnira.

[Ó lẹ] [Tirmiziy ni o gba a wa]

الشرح

Arákùnrin kan wa ba Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati wa fi ẹjọ́ bi àwọn ẹrú rẹ ṣe n hùwà sùn, pe wọn maa n pa irọ́ fun un, wọn si maa n janba rẹ nibi agbafipamọ, wọn si maa n rẹ́ ẹ jẹ nibi ibalopọ, wọn si maa n yapa àṣẹ rẹ, oun naa si maa n bu wọn, o si maa n na wọn lati kọ́ wọn ni ẹ̀kọ́, o wa bi i leere nipa bi ọrọ oun ṣe maa jẹ pẹlu wọn ni Ọjọ́ Àjíǹde? Ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Wọ́n maa ṣírò ijanba ti wọn ṣe fun ẹ, ati bi wọn ṣe yapa àṣẹ rẹ, ati irọ́ ti wọn pa fun ẹ, ati ìyà ti o fi jẹ wọn, tí ìyà ti o fi jẹ wọn ba jẹ odiwọn ẹṣẹ wọn, o o nii ni ẹsan, o o si nii jẹ ìyà, tí iya ti o fi jẹ wọn ba kere si ẹṣẹ wọn, o maa jẹ alekun ẹsan fun ẹ, ṣùgbọ́n ti iya ti o fi jẹ wọn ba ju ẹṣẹ wọn lọ, wọn maa fi iya jẹ ìwọ naa, wọn si maa gba odiwọn ti o ba le lọ́wọ́ rẹ, wọn si maa fun wọn, ni arákùnrin naa wa rìn jìnnà, o wa bẹ̀rẹ̀ si nii n sunkún ti o si n pariwo, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ fún un pé: Ṣé o o ka tira Ọlọhun ti o sọ pe: {A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. Kí (iṣẹ́) jẹ́ ìwọ̀n èso kardal (bín-íntín), A máa mú un wá. A sì tó ní Olùṣírò} [Al-Anbiyaa: 47], wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹni kankan ni Ọjọ́ Àjíǹde, àwọn òṣùwọ̀n si maa wa laarin awọn èèyàn pẹ̀lú déédéé, ni arákùnrin naa wa sọ pé: Mo fi Ọlọhun bura irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mi o ri nǹkan kan ti o ni ọla fun èmi ati awọn ju ki a pínyà lọ, mo n fi ọ jẹ́rìí pe gbogbo wọn ti di ọmọlúwàbí nítorí tí Ọlọhun; ni ti ipaya ìṣirò ati ìyà.

فوائد الحديث

Ododo saabe naa nipa fífún àwọn ẹrú rẹ ni òmìnira ni ti ipaya ìyà Ọlọhun.

Gbigba ẹ̀san lara alabosi, ti o ba ṣe deede odiwọn abosi naa, tabi ti o ba kere si i, nǹkan ti o ni ẹtọ ni, ṣùgbọ́n ki o ju u lọ, eewọ ni.

Ṣiṣenilojukokoro lori biba àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ àti àwọn ọ̀lẹ lò pọ̀ pẹlu dáadáa.

التصنيفات

Nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin., Ifọ awọn ẹmi mọ, Alaye awọn aayah