Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ mi ni ataya, ti atẹlẹwọ mi wa laaarin atẹlẹwọ rẹ mejeeji, gẹgẹ bi o ṣe maa n kọ mi ni Surah ninu Kuraani

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ mi ni ataya, ti atẹlẹwọ mi wa laaarin atẹlẹwọ rẹ mejeeji, gẹgẹ bi o ṣe maa n kọ mi ni Surah ninu Kuraani

Lati ọdọ ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ mi ni ataya, ti atẹlẹwọ mi wa laaarin atẹlẹwọ rẹ mejeeji, gẹgẹ bi o ṣe maa n kọ mi ni Surah ninu Kuraani: "At-tahiyyaatu lillah, was solawaatu wat toyyibaatu, as salaamu alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu, as-salaamu alaina wa 'alaa 'ibaadillahis soliheen, ash-hadu an laa ilaaha illallohu wa ash-hadu anna Muhammadan 'abduHu wa rosuuluHu". Ninu ẹgbawa kan ti o jẹ ti awọn mejeeji: "Dajudaju Ọlọhun ni Ọba alaafia, ti ẹnikẹni ninu yin ba jokoo nibi irun, ki o ya sọ pe: "At-tahiyyaatu lillah was solawaatu wat toyyibaatu, As-salaamu alaika ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu, as-salaamu alaina wa 'alaa'ibaadillahis soliheen. Ti o ba ti sọ ọ, o maa ba gbogbo ẹru Ọlọhun rere ni oke ati ilẹ, ash-hadu an laa ilaaha illallohu, wa ash-hadu anna Muhammadan 'abduHu wa rosuuluHu, lẹyin naa o maa ṣe ẹṣa nnkan ti o ba fẹ ninu ibeere".

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- ni ataya ti wọn maa n ka lori irun, o wa fi ọwọ rẹ si ọwọ rẹ mejeeji, lati jẹ ki o kọ ibi ara si i. Gẹgẹ bi o ṣe maa n kọ ọ ni Surah ninu Kuraani ninu nnkan ti o tọka lori iko akolekan Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si ataya yii ni gbolohun ati ni ìtumọ̀. O si sọ pe: "At-tahiyyaatu lillah": Oun ni gbogbo ọrọ ati iṣẹ ti o da lori igbetobi, gbogbo ẹ ni o tọ si Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn. "As-solawaatu": Oun ni ìrun ti a mọ, ọran-anyan rẹ ati awọn nafila rẹ jẹ ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-. "At-toyyibaatu": Òun ni awọn ọrọ ati awọn iṣẹ ati awọn iroyin ti wọn daa ti wọn si n da lori pipe, gbogbo rẹ tọ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-. "As-salaamu alaika ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu": Adura ni o jẹ fun un pẹlu lila kuro nibi gbogbo aleebu ati nnkan ti a koriira, ati alekun ati ọpọlọpọ ninu gbogbo oore. "As-salaamu alaina wa 'alaa'ibaadillahis soliheen": Adura ni o jẹ pẹlu ọlà fun olukirun ati fun gbogbo ẹru rere ni sanmọ ati ilẹ. "Ash-hadu an laa ilaaha illallohu": O n túmọ̀ si pe mo n fi i rinlẹ ni ifirinlẹ ododo pẹlu rẹ pe ko si ẹni ti a le jọsin fun lododo afi Ọlọhun. "Wa anna Muhammadan 'abduHu wa rosuuluHu": Mo n fi ijẹ ẹru ati ìránṣẹ́ ti o jẹ opin rinlẹ fun un. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe olukirun lojukokoro lati ṣe ẹṣa ninu adura ti o ba fẹ.

فوائد الحديث

Aaye ataya yii ni nibi ijokoo lẹyin ifọrikanlẹ ikẹyin nibi gbogbo irun, ati lẹyin rakah keji nibi irun olopoo mẹta ati olopoo mẹrin.

Jijẹ dandan kika At-tahiyyaatu níbi ataya, ati pe o lẹtọọ lati ka eyikeyii ẹgbawa ninu awọn ẹgbawa ataya ninu eyi ti o fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.

Nini ẹtọ ṣíṣe adura lori irun pẹlu nnkan ti o ba fẹ, lopin igba ti ko ba ti jẹ ẹṣẹ.

Ṣíṣe bibẹrẹ pẹlu ara ẹni ni nnkan ti a fẹ nibi adura.

التصنيفات

Iroyin irun