?Wọn mọ Isilaamu pa lori nkan márùn-ún

?Wọn mọ Isilaamu pa lori nkan márùn-ún

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Wọn mọ Isilaamu pa lori nkan márùn-ún: Ijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ẹru Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni, ati imaa gbe irun duro, ati imaa yọ zakah, ati imaa gbero ile Oluwa, ati gbigba aawẹ Ramadan».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fi Isilaamu jọ ile kan ti wọn mọ daadaa pẹlu origun maarun ti o gbe ile naa duro, ti awọn iwa Isilaamu ti o sẹku jẹ pipari ile naa. Akọkọ awọn origun yii ni: Ijẹrii mejeeji; ijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Rẹ ni, ati pe origun kan ni mejeeji; ti ọkan o lee ja kuro lara ìkejì, ẹru o sọ mejeeji ni ẹni ti n fi ijẹ ọkan ṣoṣo Ọlọhun ati lilẹtọọ Rẹ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo laisi ẹlòmíràn yatọ si i rinlẹ, ti yio si maa ṣiṣẹ tọ awọn nkan ti o n tọka si, ki o si tun gba iransẹ Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - gbọ ni ẹni ti yio maa tẹle e. Origun keji ni: Gbigbe irun duro, oun naa ni awọn irun ọranyan marun-un ni ojumọ kan ati oru kan: Alufajari, ati Àílà, ati Alaasari, ati Magribi, ati Ishai, pẹlu awọn majẹmu wọn ati awọn origun wọn ati awọn ọranyan wọn. Origun kẹta ni: Yiyọ zakah ọranyan, oun naa ni ijọsin owo ti o jẹ dandan nibi gbogbo dukia ti o ba ti to odiwọn ti wọn fi aala si ninu shariah, ti wọn o fun awọn ti wọn ni ẹtọ si i. Origun kẹrin ni: Hajji, oun naa ni gbigbero Makkah lati gbe awọn iṣẹ ìjọsìn duro, ni ti jijọsin fun Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn. Origun karun-un ni: Aawẹ Ramadan, oun naa ni kikoraro nibi jijẹ ati mimu ati nkan ti o yatọ si mejeeji ninu awọn nkan ti o le ba aawẹ jẹ pẹlu aniyan jijọsin fun Ọlọhun, lati igba ti alufajari ba ti yọ titi ti oorun yio fi wọ.

فوائد الحديث

Sisopapọ ijẹrii mejeeji, nitori naa ọkan ninu mejeeji o lee ni alaafia ayaafi pẹlu ikeji; fun idi eyi ni wọn fi ṣe mejeeji ni origun kan.

Ijẹrii mejeeji ni ipilẹ ẹsin, nitori naa wọn o nii tẹwọ gba ọrọ kan abi iṣẹ kan ayaafi pẹlu mejeeji.

التصنيفات

Ìgbàgbọ́ ninu Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn, Ijẹ Anọbi, Ẹsin Isilaamu, Ijẹ dandan irun ati idajọ ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, Jijẹ dandan saka yiyọ ati idajọ ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, Obligation of Fasting and Ruling of Its Abandoning, Obligation of Hajj and ‘Umrah and Ruling of Its Abandoner