?Ẹni ti o ba ka āyatul kursiyyu ni ẹyin irun ọranyan kọọkan, ko si nkan ti yio di i lọwọ wiwọ al-jannah ayaafi ki o ku

?Ẹni ti o ba ka āyatul kursiyyu ni ẹyin irun ọranyan kọọkan, ko si nkan ti yio di i lọwọ wiwọ al-jannah ayaafi ki o ku

Lati ọdọ Abu Umāmah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹni ti o ba ka āyatul kursiyyu ni ẹyin irun ọranyan kọọkan, ko si nkan ti yio di i lọwọ wiwọ al-jannah ayaafi ki o ku.

[O ni alaafia] [At-Tabaraani]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba ka āyatul kursiyyu lẹyin ipari irun ọranyan, ko si nkankan ti o le ma jẹ ki o wọ alujanna ayaafi iku; o si wa ninu sūratul Baqorah, gbolohun Ọlọhun ti ọla rẹ ti o sọ pe: {Allahu la ilaha illa Huwa al-Hayyu al-Qayyoomu la ta‘khuthuHu sinatun wala nawmun laHu ma fis samāwāti wama fil ardi man dha ladhī yashfa‘u indaHu illa bi-idhniHi ya‘lamu mā bayna aydīhim wamā khalfahum wala yuhītūna bishayin min ‘ilmiHi illa bimā shaa'a wasi‘a kursiyyuHus samāwāti wal-arda wala ya’ūduHu hifdhuhumā waHuwal ‘aliyyu alAadhīm} [Al-Baqorah: 255]

فوائد الحديث

Ọla ti o n bẹ fun aayah ti o tobi yii; latari nkan ti o ko sinu ninu awọn orukọ to rẹwa ati awọn iroyin ti o ga.

Ṣiṣe lẹtọọ kika aayah ti o tobi yẹn lẹyin gbogbo irun ọranyan.

Awọn iṣẹ oloore jẹ okunfa wiwọ al-jannah.

التصنيفات

Awọn iranti irun