إعدادات العرض
irẹ Ọlọhun mo sa di ìyọnu Rẹ kuro nibi ibinu Rẹ, mo si sa di amojukuro Rẹ kuro ni bi ijẹ níyà Rẹ". Mo tun sa di irẹ Ọlọhun pẹlu araarẹ, mi o le yin ọ tán gẹlẹ bi o ṣe yin ara Rẹ
irẹ Ọlọhun mo sa di ìyọnu Rẹ kuro nibi ibinu Rẹ, mo si sa di amojukuro Rẹ kuro ni bi ijẹ níyà Rẹ". Mo tun sa di irẹ Ọlọhun pẹlu araarẹ, mi o le yin ọ tán gẹlẹ bi o ṣe yin ara Rẹ
Lati ọdọ Aishah - ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - o sọ bayi pe: Mo ṣafẹku ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) lori ibusun loru ọjọ kan, mo wa nfi ọwọ wa a kiri bẹẹni ọwọ mi kan inu atẹlẹsẹ rẹ nigbati o wa ni iforikanlẹ, ti o gbe gigisẹ rẹ mejeeji sí oke, ti nsọ bayi ninu adura rẹ pe: "irẹ Ọlọhun mo sa di ìyọnu Rẹ kuro nibi ibinu Rẹ, mo si sa di amojukuro Rẹ kuro ni bi ijẹ níyà Rẹ". Mo tun sa di irẹ Ọlọhun pẹlu araarẹ, mi o le yin ọ tán gẹlẹ bi o ṣe yin ara Rẹ.
الترجمة
العربية Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Türkçe اردو 中文 हिन्दी Tagalog ئۇيغۇرچە Kurdî Kiswahili Português සිංහල Русский Nederlands Tiếng Việt অসমীয়া ગુજરાતી پښتو Hausa മലയാളം नेपाली ქართული Magyar తెలుగు Македонски Svenska ಕನ್ನಡ Moore አማርኛ Română Українська ไทย मराठी ਪੰਜਾਬੀ دری বাংলা Wolof ភាសាខ្មែរ Malagasyالشرح
Aishah - ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - o sọ bayi pe: mo sun lẹgbẹ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a), mo ṣe afẹku rẹ ni oru (mi o ri), mo wa fi ọwọ mi woo ni ààyè ti o ma ti nkirun ninu yàrá, bayi ni mo kan lojiji pe o nkirun lọwọ ti gigisẹ rẹ mejeeji si wa ni iduro, bẹẹ sì ni o nsọ bayi pe: (mo nwa isọ) mo nṣe atẹgun sọdọ Rẹ (pẹlu ìyọnu Rẹ kuro nibi ibinu Rẹ) sí mi tabi sí awọn ijọ mi, (ati) pe mo nwa isọra (pẹlu amojukuro Rẹ) ati amojukuro re ti o pọ (kuro nibi ijẹniya Rẹ), (mo wa idaabobo lọdọ Rẹ pẹlu araarẹ) ati pẹlu awọn iroyin rirẹwa Rẹ lọdọ awọn iroyin titobi Rẹ, nigbati o jasipe ẹnikan ò lee ṣọ ni lọdọ Rẹ àyaàfi ìwọ fún rara Rẹ, kò sibi aa salọ fún akoyọ, bẹẹ sì ni kò sibi ti a le sadi lati sa fún Ọlọhun ayaafi ki a sadi Ọlọhun, (Mi o le ṣe onka ẹyin fún irẹ Ọlọhun), mi o nikapa, mi o sì lè dé òpin ati onka lati ka gbogbo idẹra Rẹ tan nitori ikagara mi, bẹẹ ni mi o le ka daada Rẹ tan gẹgẹbi O ṣe lẹtọ si i, koda bi mo ba ṣe igbiyanju ati akitiyan láti ṣe bẹẹ, (gẹgẹ bí Irẹ Ọlọhun ṣe ṣe ẹyìn fún ara Rẹ) Iwọ ni O ṣe ẹyìn fún Pàápàá ara Rẹ, ẹyin ti o ba ọ mu, taani ẹni náà tí o ni ikapa lati mu ẹyin Rẹ wá ní bo ṣe yẹ?!فوائد الحديث
Fifẹ ki a se awọn adua yii nibi iforikanlẹ
Meirak sọ bayi pe: ninu ọkan ninu awọn ẹgbawa An-Nasaaiy: Anọbi a maa ṣe adua yi ti o ba pari irun rẹ, ti o si fi ẹgbẹ le lẹ láti sun.
Fifẹ ki a se ẹyìn fún Ọlọhun pẹlu awọn iroyin Rẹ ati imáa pe pẹlu awọn orukọ Rẹ ti o f'ẹsẹ rinlẹ nínú Al-kurani ati Sunnah Anọbi.
Igbe Ọlọhun Adẹda ga wà nibẹ nibi itẹriba ati ni iforikanlẹ.
O lẹtọ lati wá isọra (ìdáàbòbò) pẹlu awọn iroyin Ọlọhun, bẹẹ ni o lẹtọ lati wá isọra pẹlu pàápàá Rẹ, mimọ fún Ọlọhun ti O gaju lọ.
Al-Khọtọọbi sọ bayi pe: itumọ ti o lẹ̀ wa ninu ọrọ yii, ohun náà ni pe dájúdájú o ti wá isọra lọdọ Ọlọhun pe ko ṣọ ohun pẹlu ìyọnu Rẹ nibi ibinu Rẹ ati pẹlu amojukuro Rẹ nibi ijẹni-niya Rẹ, ìyọnu ati ibinu ọrọ ati ida keji niwọn (orogun meji niwọn), bẹẹ náà ni amojukuro ati ifi ọwọ iya muni, nigbati o de ibi idarukọ nkan ti ko ni idakeji Oun náà ni Allah (Ọlọhun) mimọ ni fun Ọba ti O ga jù, O wa isọra pẹlu Rẹ lọdọ ara Rẹ, ti kii se ọdọ ẹlòmíràn, ìtumọ eléyun nipe: iwa aforijin nibi aseeto ojúṣe ọranyan o wa ninu ẹto ìjọsìn fun Un ati ifi ẹyìn fun Un. Gbólóhùn rẹ to sọ pe: "mi o lẹ se onka ẹyin fún Ẹ: ìtumọ rẹ ni pé: mi o ni ikapa lati mu dé ogongo ẹyin Rẹ.
التصنيفات
Awọn iranti irun