?Ti oluperun ba sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, ti ẹnikẹni ninu yin naa wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar

?Ti oluperun ba sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, ti ẹnikẹni ninu yin naa wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar

Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Ti oluperun ba sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, ti ẹnikẹni ninu yin naa wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Hayya‘ala sọlaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Hayya‘alal falaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Laa illaha illā Allāhu, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa illaha illā Allāhu lati inu ọkan rẹ wa yio wọ aljanna».

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Irun pipe ni fifi mọ awọn eeyan wiwọle asiko irun, ati pe awọn gbolohun irun pipe jẹ awọn gbolohun ti wọn ko adisọkan igbagbọ sinu. Ati pe ninu hadīth yii Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye nkan ti wọn ṣe ni ofin nigba ti a ba n gbọ ipe irun, oun naa ni ki ẹni ti n gbọ o maa sọ gẹgẹ bi oluperun ṣe n sọ, nigba ti o ba sọ pe "Allāhu Akbar" ẹni ti o n gbọ naa maa sọ pe: "Allāhu Akbar", bayii ni yio ṣe maa lọ; ayaafi nigba ti oluperun ba sọ pe "ayya‘ala sọlaah", "ayya‘alal falaah", nigba naa ẹni ti n gbọ maa sọ pe: "Laa haola walā quwwata illā biLlāh". Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - si tun ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba paara nkan ti oluperun n wi ni ti imọkanga lati inu ọkan rẹ yio wọ alujanna. Itumọ awọn gbolohun irun pipe ni: "Allāhu Akbar": Itumọ rẹ ni pe dajudaju Oun mimọ fun Un ni O tobi julọ, Oun ni o si tun gbọnngbọn ju gbogbo nkan lọ. "Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu ": Itumọ rẹ ni pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu. "Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah": Itumọ rẹ ni pe mo n fi rinlẹ mo si tun n jẹrii pẹlu ahọn mi ati ọkan mi pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn ran an ni'ṣẹ, ti itẹle e si jẹ dandan. "Hayya‘ala sọlaah", itumọ rẹ ni pe ẹ wa lọ ki irun, ati pe gbogbo olugbọ yio sọ pe: "Laa haola walā quwwata illā biLlāh", itumọ rẹ ni pe ko si ète kankan lati la kuro nibi awọn nkan ti maa n dena titẹle aṣẹ, kò sì tun si agbara lati ṣe e, bẹẹ ni ko si ikapa lori ikankan ninu awọn nkan wọnyii ayaafi pẹlu kongẹ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga. "Hayya‘alal falaah", itumọ rẹ ni pe ẹ wa sibi okunfa ọla, oun naa ni jijere pẹlu alujanna ati lila kuro nibi ina.

فوائد الحديث

Ọla ti o wa fun imaa fesi fun oluperun pẹlu sisọ iru nkan ti o n sọ, ayaafi nibi hayya‘ala mejeeji (hayya‘ala solaah ati hayya‘alal falaah), nigba naa yio sọ pe: "Laa haola walā quwwata illā biLlāh".

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun iranti, Awọn ọla ti n bẹ fun iranti, Irun pipe ati Iqoomoh, Irun pipe ati Iqoomoh