إعدادات العرض
sọ ọrọ kan fun mi ninu Isilaamu ti mi ko nii bi ẹnikẹni leere nípa rẹ yàtọ̀ si ẹ, o sọ pe: "Sọ pe: Mo gbagbọ ninu Ọlọhun, lẹyin naa ki o duro deedee
sọ ọrọ kan fun mi ninu Isilaamu ti mi ko nii bi ẹnikẹni leere nípa rẹ yàtọ̀ si ẹ, o sọ pe: "Sọ pe: Mo gbagbọ ninu Ọlọhun, lẹyin naa ki o duro deedee
Lati ọdọ baba Hamur - wàn tilẹ sọ pé Bàbá Hamrata ni - , òun ni Sufyan ọmọ Abdullahi kí Ọlọhun yọnu sí o sọ pé: Mo sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, sọ ọrọ kan fun mi ninu Isilaamu ti mi ko nii bi ẹnikẹni leere nípa rẹ yàtọ̀ si ẹ, o sọ pe: "Sọ pe: Mo gbagbọ ninu Ọlọhun, lẹyin naa ki o duro deedee".
الترجمة
العربية Español አማርኛ English اردو Indonesia ئۇيغۇرچە বাংলা Français Türkçe Русский Bosanski සිංහල हिन्दी 中文 فارسی Tiếng Việt Tagalog Kurdî Hausa Português മലയാളം తెలుగు Kiswahili தமிழ் မြန်မာ ไทย Deutsch 日本語 پښتو অসমীয়া Shqip Svenska Nederlands ગુજરાતી Кыргызча नेपाली Lietuvių دری Српски Soomaali тоҷикӣ Kinyarwanda Română Magyar Čeština Moore Malagasy Oromoo ಕನ್ನಡ Wolof Azərbaycan O‘zbek Українська ქართული Македонски ភាសាខ្មែរ Bambara ਪੰਜਾਬੀ मराठी Kirundi Kurmancî Bahasa Melayu Yaoالشرح
Saabe Sufyan ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere lati kọ oun ni ọrọ kan ti o ko awọn ìtumọ̀ Isilaamu sinu, ti oun maa dirọ mọ ọn, ti oun ko si nii bi ẹni ti o yàtọ̀ si i leere nipa rẹ? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: sọ pe Mo mu Ọlọhun lọkan, mo si gbagbọ pe Oluwa mi ni ati Ọlọhun mi ati Aṣẹ̀dá mi ati Ẹni ti maa maa jọsin fun lododo ti ko si orogun fun Un, Lẹyin naa, yoo tẹ fun itẹle Ọlọhun pẹlu ṣíṣe awọn ọran-anyan Ọlọhun ati gbigbe awọn eewọ Ọlọhun ju silẹ ti yoo si maa tẹsiwaju lori rẹ.فوائد الحديث
Ipilẹ ẹsin ni nini igbagbọ ninu Ọlọhun pẹlu ijẹ Oluwa Rẹ ati ijẹ Ọlọhun Rẹ ati awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ.
Pataki iduro ṣinṣin lẹyin igbagbọ, ati itẹsiwaju nibi ijọsin, ati fifi ẹsẹ rinlẹ lori ìyẹn.
Igbagbọ jẹ majẹmu itẹwọgba awọn iṣẹ.
Nini igbagbọ ninu Ọlọhun, ko nnkan ti adisọkan rẹ jẹ dandan sinu ninu awọn adisọkan igbagbọ ati awọn ipilẹ rẹ, ati nnkan ti o tẹle ìyẹn ninu awọn iṣẹ ọkan, ati itẹle ati gbigba fun Ọlọhun ni kọkọ ati ni gbangba.
Iduro ṣinṣin ni ki èèyàn má kúrò ni oju ọna, pẹlu ṣíṣe awọn nnkan ti wọn jẹ dandan ati gbigbe awọn nnkan ti a kọ ju silẹ.
