Akọkọ nnkan ti wọn maa ṣe idajọ rẹ laaarin awọn eniyan ni ọjọ igbedide ni nibi awọn ẹjẹ

Akọkọ nnkan ti wọn maa ṣe idajọ rẹ laaarin awọn eniyan ni ọjọ igbedide ni nibi awọn ẹjẹ

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Akọkọ nnkan ti wọn maa ṣe idajọ rẹ laaarin awọn eniyan ni ọjọ igbedide ni nibi awọn ẹjẹ".

[O ni alaafia] [Al-Bukhari and Muslim. This is the wording of Muslim]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju akọkọ nnkan ti wọn maa ṣe idajọ rẹ laaarin awọn eniyan nibi abosi apa kan si apakan ni ọjọ igbedide ni: Nibi awọn ẹjẹ, gẹgẹ bii pipa ènìyàn ati awọn ọgbẹ.

فوائد الحديث

Titobi àlámọ̀rí awọn ẹjẹ, nitori pe ìbẹ̀rẹ̀ maa n jẹ pẹlu eyi ti o ṣe pataki julọ.

Awọn ẹṣẹ maa tobi ni ibamu si titobi ibajẹ ti o wa nibẹ, ati ita awọn ẹmi alaiṣẹ silẹ wa ninu eyi ti o tobi julọ ninu ibajẹ, ko si eyi ti o tobi ju u lọ afi ṣíṣe aigbagbọ ati dida orogun pọ mọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.

التصنيفات

Isẹmi ọjọ ìkẹyìn, Gbigba ẹsan