Eyi ti o loore julọ ninu ọjọ ti oorun yọ nibẹ ni ọjọ Jímọ̀

Eyi ti o loore julọ ninu ọjọ ti oorun yọ nibẹ ni ọjọ Jímọ̀

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Eyi ti o loore julọ ninu ọjọ ti oorun yọ nibẹ ni ọjọ Jímọ̀, ninu rẹ ni wọn ṣẹda Aadam, ninu rẹ ni wọn mu u wọ alujanna, ninu rẹ ni wọn mu u jade kúrò nibẹ, ọjọ́ igbende ko lee to afi ni ọjọ Jimọ".

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju eyi ti o daa julọ ninu ọjọ ti oorun ran ninu rẹ ni ọjọ Jimọ, Ninu awọn iroyin rẹ ti o fi da yatọ ni pe: Dajudaju Ọlọhun ṣẹda Aadam- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- ninu rẹ, ninu rẹ ni O mu u wọnu alujanna, ninu rẹ ni O mu u jade lati inu rẹ ti O si mu u sọkalẹ sori ilẹ̀, ọjọ igbende ko lee to afi ni ọjọ Jimọ.

فوائد الحديث

Ọla ti o n bẹ fun ọjọ Jimọ lori awọn yoku ninu awọn ọjọ ọsẹ.

Ṣisẹnilojukokoro ati jijẹ ki awọn iṣẹ oloore pọ ni ọjọ jimọ, ati igbaradi fun riri ikẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati titi ifiyajẹ rẹ danu.

Awọn iroyin ti Jimọ fi da yatọ ti wọn dárúkọ ninu hadiiisi náà, wọn sọ pé: Ko wa fun didárúkọ ọla ti o n bẹ fun Jimọ; nitori pe imujade Aadam ati tito ọjọ igbende wọn ko ka a si ọla, wọn sọ pé: Bi ko ṣe pe gbogbo rẹ jẹ ọla ti jijade Aadam si jẹ okunfa bibẹ arọmọdọmọ ninu awọn ojiṣẹ ati awọn anabi ati awọn ẹni rere, ati pe tito ọjọ igbende jẹ okunfa yiyara gbigba ẹsan awọn ẹni rere ati titẹwọ gba nnkan ti Ọlọhun ti pese fun wọn ninu awọn apọnle.

Wọn dárúkọ awọn iroyin miiran ti ọjọ Jimọ fi da yàtọ̀, yàtọ̀ si eyi ti wọn dárúkọ ninu ẹgbawa yìí, ninu rẹ ni: Ninu rẹ ni wọn gba ironupiwada Aadam, ninu rẹ ni wọn gba ẹmi rẹ, ninu rẹ ni wakati kan wa ti ẹru kan ti o jẹ olugbagbọ ko nii ṣe kongẹ rẹ ti o si n kirun ti o n beere nnkan kan lọdọ Ọlọhun afi ki O fun un ni nnkan naa.

Eyi ti o lọla julọ ninu awọn ọjọ inu ọdun ni ọjọ 'Arafah, wọn sọ pé: Ọjọ́ iduran (ọdun ileya), ti eyi ti o lọla julọ ninu awọn ọjọ ọsẹ si jẹ ọjọ Jimọ, ti eyi ti o lọla julọ ninu oru si jẹ oru abiyi (lailatul qadri).

التصنيفات

Àwọn Anọbi ati awọn ojiṣẹ ti wọn ṣíwájú, ki àlàáfíà maa ba wọn