إعدادات العرض
1- Ẹ fi mi sílẹ̀ lópin ìgbà tí mo ba fi yin sílẹ̀, dajudaju nnkan ti o pa awọn ti wọn ṣáájú yin run ni ibeere wọn ati iyapa wọn si awọn anabi wọn
2- Eyi ti o loore julọ ninu ọjọ ti oorun yọ nibẹ ni ọjọ Jímọ̀
3- Mo fi ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, o maa ku díẹ̀ ki ọmọ Maryam sọkalẹ si aarin yin ni adajo oluṣedeedee, ti o maa run agbelebuu, ti o maa pa ẹlẹ́dẹ̀, ko nii jẹ ki wọn san isakọlẹ mọ, ti owo maa pọ̀ titi ẹni kankan ko fi nii gba a mọ