Mo fi ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, o maa ku díẹ̀ ki ọmọ Maryam sọkalẹ si aarin yin ni adajo oluṣedeedee, ti o maa run agbelebuu, ti o maa pa ẹlẹ́dẹ̀, ko nii jẹ ki wọn san isakọlẹ mọ, ti owo maa pọ̀ titi ẹni kankan ko fi nii gba a mọ

Mo fi ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, o maa ku díẹ̀ ki ọmọ Maryam sọkalẹ si aarin yin ni adajo oluṣedeedee, ti o maa run agbelebuu, ti o maa pa ẹlẹ́dẹ̀, ko nii jẹ ki wọn san isakọlẹ mọ, ti owo maa pọ̀ titi ẹni kankan ko fi nii gba a mọ

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Mo fi ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, o maa ku díẹ̀ ki ọmọ Maryam sọkalẹ si aarin yin ni adajo oluṣedeedee, ti o maa run agbelebuu, ti o maa pa ẹlẹ́dẹ̀, ko nii jẹ ki wọn san isakọlẹ mọ, ti owo maa pọ̀ titi ẹni kankan ko fi nii gba a mọ".

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n bura lori sisunmọ sisọkalẹ Isa ọmọ Maryam- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- lati maa ṣe idajọ laaarin awọn eniyan pẹlu deedee pẹlu Sharia ti Muhammad, Ati pe o maa pada run agbelebuu ti awọn Nasara n gbe tobi, Atipe Isa- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- maa pa ẹlẹ́dẹ̀, Ati pe Isa- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- ko nii jẹ ki wọn san isakọlẹ mọ, o si maa jẹ ki gbogbo èèyàn wọnú Isilaamu. Ati pe dajudaju owo maa pada maa da ti ẹni kankan ko nii gba a; ìyẹn maa rí bẹ́ẹ̀ fun pipọ rẹ, ati rirọrọ gbogbo ẹni kọọkan pẹlu nnkan ti o n bẹ ni ọwọ rẹ mejeeji, ati sisọkalẹ alubarika ati itẹle-ara-wọn awọn oore.

فوائد الحديث

Fifi sisọkalẹ Isa- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- rinlẹ ni igbẹyin ìgbà, ati pe o wa ninu awọn ami ọjọ igbende.

Sharia Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- eyi ti o yàtọ̀ si i ko lee pa a rẹ.

Sisọkalẹ awọn alubarika sibi owo ni igbẹyin igba, pẹlu irayesa awọn eniyan nibẹ.

Iro idunnu pẹlu ṣiṣẹku ẹsin Isilaamu nigba ti Isa- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- maa ṣe idajọ pẹlu rẹ ni igbẹyin igba.

التصنيفات

Àwọn Anọbi ati awọn ojiṣẹ ti wọn ṣíwájú, ki àlàáfíà maa ba wọn, Anọbi wa Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, Isẹmi inu sàréè, Ijẹ gbogbogboo ẹsin Isilaamu