Òjíṣẹ Ọlọhun (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa ba) aa maa se igbiyanju ni mẹwa igbẹyin iru igbiyanju ti kii se ninu awọn ọjọ miran

Òjíṣẹ Ọlọhun (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa ba) aa maa se igbiyanju ni mẹwa igbẹyin iru igbiyanju ti kii se ninu awọn ọjọ miran

Lati ọdọ Aishah iya awọn olugbagbọ ododo, ki Ọlọhun yọnu si i: Òjíṣẹ Ọlọhun (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa ba) aa maa se igbiyanju ni mẹwa igbẹyin iru igbiyanju ti kii se ninu awọn ọjọ miran.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Ti mẹwa igbẹyin ninu osu Ramadan ba tide Anọbi (Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba) aa maa gbiyanju ninu rẹ pẹlu ìjọsìn ati itẹle aṣẹ Ọlọhun, aa si maa se ọpọlọpọ awọn oriṣirisi iṣẹ o loore ati awọn oníranran iṣẹ daada ati ìjọsìn fún Ọlọhun eyi ti o pọ ju bi se ma ngbiyanju ni awọn ọjọ míràn lọ, ori bẹẹ nitori titobi ati ọlá ti nbẹ fún awọn òru náà ati nítorí wiwa òru abiyi.

فوائد الحديث

Iseni lójúkòkòrò lati se ọpọlọpọ iṣẹẹre ati awọn ọna itẹle aṣẹ Ọlọhun ninu osu Ramadan lapapọ ati ni mẹwa igbẹyin ninu rẹ ni adayanri.

Mẹwa igbẹyin ninu osu Ramadan aa maa bẹrẹ lati òru ọkanlelogun titi di ipari oṣù.

ifẹ ki a lo anfaani awọn asiko ti o lọ́lá fún itẹle aṣẹ Ọlọhun.

التصنيفات

‏Awọn mẹwa igbẹyin inu Ramadan