إعدادات العرض
Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu ẹṣẹ lo tobi julọ lọdọ Ọlọhun? O sọ pe: "Ki o wa orogun fun Ọlọhun ti o si jẹ pe Oun ni O ṣẹda rẹ
Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu ẹṣẹ lo tobi julọ lọdọ Ọlọhun? O sọ pe: "Ki o wa orogun fun Ọlọhun ti o si jẹ pe Oun ni O ṣẹda rẹ
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu ẹṣẹ lo tobi julọ lọdọ Ọlọhun? O sọ pe: "Ki o wa orogun fun Ọlọhun ti o si jẹ pe Oun ni O ṣẹda rẹ" mo sọ pe: Dajudaju ìyẹn tobi, mo sọ pe: Lẹyin naa èwo tún ni? O sọ pe: "Ki o pa ọmọ rẹ; ti o n bẹru ki o maa jẹun pẹlu rẹ" mo sọ pe: Lẹyin naa èwo tún ni? O sọ pe: "Ki o ba iyawo ara adugbo rẹ ṣe ṣìná".
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Kurdî Hausa Português മലയാളം తెలుగు Kiswahili தமிழ் မြန်မာ Deutsch 日本語 پښتو Tiếng Việt অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ ئۇيغۇرچە සිංහල ไทย دری Кыргызча or Kinyarwanda नेपाली Malagasy Română Lietuvių Oromoo Nederlands Soomaali Српски Українська ಕನ್ನಡ Wolof Mooreالشرح
Wọn bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa eyi ti o tobi julọ ninu awọn ẹṣẹ, ó wa sọ pe: Eyi ti o tobi julọ ninu wọn ni ẹbọ ńlá, oun ni ki o wa akẹgbẹ tabi afijọ fun Ọlọhun nibi ijẹ Ọlọhun Rẹ tabi nibi jijẹ Oluwa Rẹ tabi nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ, ati pe ẹṣẹ yìí, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko nii ṣe aforijin rẹ afi pẹlu ironupiwada, ti ẹni ti o ba ṣe e ba ku, o maa ṣe gbere ninu ina. Lẹyin naa, ki ọmọniyan pa ọmọ rẹ ni ti ipaya pe ki o maa jẹun pẹlu rẹ, ati pe pipa ẹmi jẹ eewọ, ṣùgbọ́n ẹṣẹ rẹ maa tobi ti ẹni ti wọn pa ba jẹ mọlẹbi ẹni ti o pa ènìyàn, ẹṣẹ rẹ maa tobi bakannaa nigba ti o ba ṣe pe erongba ẹni ti o pa eniyan naa ba pa a nitori ipaya ki ẹni ti wọn pa ma baa ba pin ninu arisiki Ọlọhun. Lẹyin naa, ki ọkùnrin ba iyawo ara adugbo rẹ ṣe ṣina, bii ki o gbiyanju lati tan iyawo ara adugbo rẹ titi o fi maa ba a ṣe ṣina ti yoo si gbà fun un, Ati pe ṣina jẹ eewọ, ṣùgbọ́n ẹṣẹ rẹ maa tobi ti ẹni tí wọ́n bá ṣe ṣina ba jẹ iyawo ara adugbo ti Sharia pàṣẹ ṣíṣe daadaa si i ati wiwu iwa daadaa si i ati biba a lo lọna ti o daa.فوائد الحديث
Jijuralọ awọn ẹṣẹ nibi títóbi, gẹgẹ bi awọn iṣẹ oloore naa ṣe maa n ju ara wọn lọ nibi ọla.
Eyi ti o tobi julọ ninu awọn ẹṣẹ ni: Imu orogun pọ mọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, lẹyin naa pipa ọmọ nitori ipaya ki o maa jẹun pẹlu rẹ, lẹyin naa ki o ṣe ṣina pẹlu iyawo ara adugbo rẹ.
Arisiki wa lọwọ Ọlọhun, Ọlọhun- mimọ ni fun Un- si ti mu ìpèsè arisiki awọn ẹda da wa lójú.
Titobi iwọ ara adugbo, ati pe dajudaju fifi suta kan an tobi ni ti ẹṣẹ ju fifi suta kan ẹni ti o yàtọ̀ si i lọ.
Aṣẹda ni Ẹni ti O lẹtọọ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un.
التصنيفات
Taohiid ti rubuubiyyah