إعدادات العرض
Ẹnikan ninu yin ko gbọ ku ayaafi ki o ni àbá daada si Ọlọhun
Ẹnikan ninu yin ko gbọ ku ayaafi ki o ni àbá daada si Ọlọhun
Lati ọdọ Jaabir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé: mo gbọ tí Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - sọ ni ọdun mẹta síwaju koto fi ayé silẹ báyi pé: "Ẹnikan ninu yin ko gbọ ku ayaafi ki o ni àbá daada si Ọlọhun".
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Tiếng Việt සිංහල Hausa Kurdî Kiswahili Português தமிழ் Nederlands অসমীয়া ગુજરાતી پښتو മലയാളം नेपाली ქართული Magyar తెలుగు Македонски Svenska Moore Română Українська ไทย मराठी ਪੰਜਾਬੀ دری አማርኛ Wolof ភាសាខ្មែរ ಕನ್ನಡالشرح
Anọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) gba musulumi níyànjú lati má kùú ayaafi ki o ni àbá daada si Ọlọhun pẹlu ki o fi abala inireti sọdọ Ọlọhun leke nígbàtí nba pọka iku lọwọ n'ireti pe Ọlọhun Yóò ṣekẹ rẹ yóò ṣe amojukuro fún un; nitoripe ifoya ni nkan ti wọn beere fún ki a le ri iṣẹ se daada, ìṣesí un kii se iṣesí iṣẹ ṣiṣe, nkan ti wọn fẹ nibẹ ni ki ireti borí.فوائد الحديث
Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nifẹ si ki o máa ṣe itọsọna fún àwọn ọmọlẹyin rẹ ati àánu rẹ tó pọ sí wọn ni gbogbo iṣesí wọn; titi o fi de ààrẹ ti o se gbẹyin o ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ìjọ rẹ o si ntọka wọn sí awọn ọna ìgbàlà tabi àkóyọ.
At-tiibiyy sọ pé: ẹ se iṣẹ yín daada ni sinyin ki aba yin si Ọlohun le da nigbati iku ba dé, nitoripe ẹni tí iṣẹ rẹ ò ba dáa siwaju ki iku to de aba rẹ konii da nigbati iku ba dé.
Èyí tí o pe ju ni iṣẹ fún ẹrú ni iṣẹ to dọgba ireti ati ifoya, ati ki ìfẹ lékè, ìfẹ ni nkan imugun, ireti ni ẹni ti ndari re, ifoya ni ẹni ti nwa a, Ọlọhun ni yóò mú ni dé bẹ pẹlu aanu Rẹ àti ọrẹ Rẹ.
o da fún ẹni tí o ba sunmọ ent o pọ k'a iku lọwọ kí o máa fi ìrètí lékè fún ati ìní ẹrọ to dá sí Ọlọhun, ninu hadith yi Anọbi kí ikẹ Olohun àti Ọlá Rẹ má dájú dájú o sọ bẹ nigbati ti o ku odun mẹta ti yóò ku.
التصنيفات
Awọn iṣẹ ọkan