Kòsí ijọkan ti wọn yóò dide láti ibi jokolẹ kan láì dárúkọ Ọlọhun níbẹ ayaafi ki wọn didi bi àpèjúwe okunbete Kẹtẹkẹtẹ, bẹẹ ni yóò tún jẹ ìbànújẹ́ fún wọn

Kòsí ijọkan ti wọn yóò dide láti ibi jokolẹ kan láì dárúkọ Ọlọhun níbẹ ayaafi ki wọn didi bi àpèjúwe okunbete Kẹtẹkẹtẹ, bẹẹ ni yóò tún jẹ ìbànújẹ́ fún wọn

Lati ọdọ Abu Hurayrah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a) sọ pe: "Kòsí ijọkan ti wọn yóò dide láti ibi jokolẹ kan láì dárúkọ Ọlọhun níbẹ ayaafi ki wọn didi bi àpèjúwe okunbete Kẹtẹkẹtẹ, bẹẹ ni yóò tún jẹ ìbànújẹ́ fún wọn.

[O ni alaafia] [Abu Daud ni o gba a wa]

الشرح

Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa niro pe kò ní sí awọn apapọ eniyan kan tí wọn joko sí ààyè ijoko kan ti wọn wa dìde láì dárúkọ Ọlọhun nibẹ àyàafi ki wọn dide gẹgẹ bí àwọn ti wọn ko jọ lórí òku kẹtẹkẹtẹ ni ori akitan ati aye oorùn; eleyi ri bẹ nítorípé wọn ṣe airoju kuro nibi ìrántí Ọlọhun, ijoko naa yoo jẹ ìbànújẹ́ fun wọn lọjọ igbende, yoo si jẹ abuku ati àbámọ ti yóò maa wà pẹlu wọn.

فوائد الحديث

ohun tí wọn sọ nípa isọni lára kúrò níbi ìgbàgbéra níbi ìrántí Ọlọhun, kò mọ lórí àwọn ààyè ijoko nikan, ṣugbọn o kari gbogbo ẹ, An-nawawiy sọ pé: wọn korira fún ẹni tí o ba joko ní ààyè kan ki o wa fi ààyè náà silẹ láì darukọ tàbí se irántí Ọlọhun ti O ga jù níbẹ.

Ìbànújẹ́ ti yóò ṣẹlẹ sí wọn ní ọjọ igbende: ninu ko jẹ pé pipadanu ẹsan ati laada nítorípé wọn ko se anfaani pẹlu àsìkò fún itẹle aṣẹ Ọlọhun, tabi ki o je ẹsẹ ati iya nitoripe wọn lo asiko síbi iyapa Ọlọhun.

Iṣe ìkìlọ̀ yi ni to bá ṣe pé ìgbàgbéra yi waye latara awọn nkan to lẹtọ, báwo ni yóò seri ti o ba waye látara awọn ijoko ti wọn se leewọ eyiti iṣọrọ ẹni lẹyìn ati òfófó ati bẹẹ bẹẹ lọ wà níbẹ?!.

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun iranti