Dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn maa n tẹ ọwọ Rẹ ni oru lati gba tuuba ẹni ti o ba da ẹṣẹ ni ọsan, O si tun maa n tẹ ọwọ Rẹ ni ọsan lati gba tuuba ẹni ti o da ẹṣẹ ni oru titi oorun o fi yọ ni ibi ti o ti maa n wọ

Dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn maa n tẹ ọwọ Rẹ ni oru lati gba tuuba ẹni ti o ba da ẹṣẹ ni ọsan, O si tun maa n tẹ ọwọ Rẹ ni ọsan lati gba tuuba ẹni ti o da ẹṣẹ ni oru titi oorun o fi yọ ni ibi ti o ti maa n wọ

Lati ọdọ Abu Mūsa - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn maa n tẹ ọwọ Rẹ ni oru lati gba tuuba ẹni ti o ba da ẹṣẹ ni ọsan, O si tun maa n tẹ ọwọ Rẹ ni ọsan lati gba tuuba ẹni ti o da ẹṣẹ ni oru titi oorun o fi yọ ni ibi ti o ti maa n wọ».

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n funni ni iro pe: Dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa n gba tituuba awọn ẹru rẹ, ti ẹru ba da ẹṣẹ kan ni ọsan ti o si tuuba ni oru Ọlọhun o gba tuuba rẹ, ti o ba si da ẹsẹ ni oru ti o wa tuuba ni ọsan Ọlọhun a gba tuuba rẹ, Ọba ti mimọ n bẹ fun Un maa n tẹ ọwọ Rẹ fun tuuba ni ti ìdùnnú si i ati gbigba a, ati pe ilẹkun tituuba o yẹ ni nkan ti wọn maa ṣi silẹ titi oorun o fi yọ nibi ti o ti n wọ ni ti ikede titan ayé, ti o ba ti wa yọ dajudaju ilẹkun tituuba ti di titi niyẹn.

فوائد الحديث

Gbigba tuuba n tẹ síwájú lopin ìgbà tí ilẹkun rẹ ba si wa ni ṣiṣi silẹ, ati pe wọn maa ti ilẹkun rẹ pẹlu yiyọ oorun ni ibuwọ rẹ, ati pe ki ọmọniyan o tuuba siwaju ipọka iku, oun naa ni ki ẹmi de ọ̀nà ọ̀fun.

Ki eeyan ma sọ ìrètí nu torí ẹṣẹ, dajudaju amojukuro Ọlọhun ti mimọ n bẹ fun Un ati ikẹ Rẹ nkan ti o gbaaye ni, ati pe ilẹkun tituuba wa ni ṣiṣi silẹ.

Awọn majẹmu tituuba: Akọkọ: Jijawọ kuro ninu ẹṣẹ, ẹlẹẹkeji: kika abamọ l'ori ṣiṣe é, ẹlẹẹkẹta: Ìpinnu lati ma pada si ibẹ mọ láéláé, eyi ni nibi awọn ẹtọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, amọ ti o ba wa sokọ mọ ẹtọ awọn ẹru, nigba naa wọn ṣe e ni majẹmu tituuba ki o da ẹtọ yẹn pada si ọdọ ẹni ti o ni i, tabi ki ẹni ti o ni ẹtọ yẹn o yaafi rẹ.

التصنيفات

Ironupiwada