?Ẹsẹ mejeeji ẹru kan ko nii yẹ ni ọjọ igbedide titi ti wọn o fi bi i nipa ọjọ ori rẹ nibo ni o pari rẹ si, ati nipa imọ rẹ kini o fi ṣe, ati nipa dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ati pe nibo ni o na an si, ati nipa ara rẹ nibo ni o lo o si

?Ẹsẹ mejeeji ẹru kan ko nii yẹ ni ọjọ igbedide titi ti wọn o fi bi i nipa ọjọ ori rẹ nibo ni o pari rẹ si, ati nipa imọ rẹ kini o fi ṣe, ati nipa dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ati pe nibo ni o na an si, ati nipa ara rẹ nibo ni o lo o si

Lati ọdọ Abu Barzata Al-aslamiy - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹsẹ mejeeji ẹru kan ko nii yẹ ni ọjọ igbedide titi ti wọn o fi bi i nipa ọjọ ori rẹ nibo ni o pari rẹ si, ati nipa imọ rẹ kini o fi ṣe, ati nipa dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ati pe nibo ni o na an si, ati nipa ara rẹ nibo ni o lo o si».

[O ni alaafia] [Tirmiziy ni o gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju ẹnikẹni ninu awọn eeyan ko nii tayọ aaye iṣiro iṣẹ ni ọjọ igbedide lọ si alijanna tabi ina titi ti wọn o fi bi i nipa awọn alamọri kan: Alakọkọọ: Iṣẹmi rẹ nibo ni o pari rẹ sí? Ẹlẹẹkeji: Imọ rẹ njẹ o wa a nitori ti Ọlọhun? Ati pe njẹ o fi ṣiṣẹ ṣe? Ati pe njẹ o mu un de ọdọ ẹni ti o lẹtọọ si i? Ẹlẹẹkẹta: Dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ṣe nibi ẹtọ ni abi níbi eewọ? Ati pe nibo ni o na an si, ṣe ibi nkan ti o yọ Ọlọhun ninu ni abi ibi ti o bi I ninu? Ẹlẹẹkẹrin: Ara rẹ ati agbara rẹ ati alaafia rẹ ati ọdọ rẹ nibo ni o lo o si?

فوائد الحديث

Ṣiṣeni ni ojukokoro lori lilo iṣẹmi s'ibi nkan ti yio yọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ninu.

Awọn idẹra Ọlọhun pọ lori awọn ẹru, ati pe yio bi i leere nipa idẹra eleyii ti o wa ninu rẹ, nitori naa o jẹ dandan fun un ki o gbe awọn idẹra Ọlọhun sí ibi tí yio yọ Ọ ninu.

التصنيفات

Isẹmi ọjọ ìkẹyìn