“Kii ṣe ara wa ẹni ti o ba retí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú láti ara nǹkan tabi ti wọn ba a ṣe e, tabi ẹni ti o ba pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ tabi ti wọn sọ imọ kọ̀kọ̀ fun, tabi ẹni ti o ba sà sí èèyàn tabi ti wọn ba a sà sí èèyàn

“Kii ṣe ara wa ẹni ti o ba retí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú láti ara nǹkan tabi ti wọn ba a ṣe e, tabi ẹni ti o ba pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ tabi ti wọn sọ imọ kọ̀kọ̀ fun, tabi ẹni ti o ba sà sí èèyàn tabi ti wọn ba a sà sí èèyàn

Lati ọdọ Imraan ọmọ Husayn- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Kii ṣe ara wa ẹni ti o ba retí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú láti ara nǹkan tabi ti wọn ba a ṣe e, tabi ẹni ti o ba pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ tabi ti wọn sọ imọ kọ̀kọ̀ fun, tabi ẹni ti o ba sà sí èèyàn tabi ti wọn ba a sà sí èèyàn, ati ẹni tí ó bá ta kókó kan, ẹni tí ó bá wa ba ẹni tí n pe apemọra imọ kọ̀kọ̀, ti o wa gba ohun ti o sọ gbọ́, onítọ̀hún ti ṣe aigbagbọ si nǹkan ti wọn sọ̀kalẹ̀ fun Muhammad, ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a”.

[O daa] [Al-Bazzaar ni o gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe adehun iya fun ẹni ti o ba ṣe àwọn nǹkan kan ninu ijọ rẹ pẹlu gbólóhùn rẹ pe: “Kii ṣe ara wa”, ninu rẹ naa ni: Akọkọ: “Ẹni ti o ba retí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú láti ara nǹkan tabi ti wọn ba a ṣe e”, ipilẹ rẹ ni: Titu ẹyẹ sílẹ̀ nígbà tí èèyàn ba fẹ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ kan bii ìrìn-àjò, tabi òwò, ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti o ba fò lọ si apá ọ̀tún, o maa retí ìṣẹ̀lẹ̀ rere, o si maa ṣe nǹkan ti o gbèrò láti ṣe, ti o ba wa fò lọ sí apá òsì, o maa retí aburú, ko si nii ṣe nnkan ti o gbero lati ṣe mọ, ko ni ẹtọ ki èèyàn ṣe èyí fúnra rẹ, tabi ki o ni ki ẹlòmíràn ba oun ṣe e, ìrètí ìṣẹ̀lẹ̀ aburu latara èyíkéyìí nǹkan maa ko sínú ìyẹn, yálà nǹkan ti a n gbọ́ ni tabi nǹkan ti a n rí, bii ẹyẹ, tabi awọn ẹranko, tabi awọn alaabọ ara, tabi nọmba, tabi awọn ọjọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ẹẹkeji: “Ẹni ti o ba pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ tabi ti wọn sọ imọ kọ̀kọ̀ fun”, ẹni tí ó bá pe apemọra imọ kọkọ pẹlu lílo ìràwọ̀ ati nǹkan mìíràn, tabi ti o wa si ọdọ ẹni ti n pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ bii adágbigba ati ẹni ti o jọ ọ, ti o wa gba ohun ti o n sọ gbọ́ pẹ̀lú pipe apemọra imọ kọ̀kọ̀, o ti ṣe aigbagbọ si nǹkan ti wọn sọ̀kalẹ̀ fun Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a). Ẹẹkẹta: “Ẹni ti o ba sà sí èèyàn tabi ti wọn ba a sà sí èèyàn”, oun naa ni ẹni tí o ṣe oogun funra rẹ, tabi o ni ki ẹlòmíràn ba oun ṣe e; lati fi ṣe ẹnikan ni anfaani, tabi ko inira bá a, tabi ti o ta kókó kan pẹlu dídi òwú ati oogun le e lori pẹlu kika àwọn gbólóhùn iṣọra ti o jẹ eewọ le e lori, ki o tun wa fẹnu fátẹ́gùn túẹ́túẹ́ sínú rẹ.

فوائد الحديث

Dandan ni igbarale Ọlọhun, ati ìgbàgbọ́ ninu kadara Rẹ, ati ṣíṣe ìrètí aburú latara nǹkan, ati oogun, ati apemọra ìní-ìmọ̀ kọ̀kọ̀ tabi bíbéèrè lọ́wọ́ àwọn ti wọn n ṣe e - ni eewọ.

Apemọra imọ kọ̀kọ̀ wa ninu ẹbọ ti o tako ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan.

Ṣíṣe gbigba àwọn adagbigba ni olódodo ni eewọ ati lílọ ba wọn, a maa lẹ̀ papọ̀ mọ́ ìyẹn àwọn nǹkan mìíràn bii kíkà nǹkan ti a n pe ni atẹlẹwọ, ati ife ìmumi, ati awọn ìràwọ̀, ati wíwò wọ́n, kódà ki o kan jẹ́ láti mọ̀ nipa wọn lásán ni.

التصنيفات

Awọn nnkan ti wọn maa n ba Isilaamu jẹ, Awọn ibeere asiko aimọkan