“Nígbà tí Ọlọhun da alujanna ati ina, O ran Jibril- ki ọla

“Nígbà tí Ọlọhun da alujanna ati ina, O ran Jibril- ki ọla

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Nígbà tí Ọlọhun da alujanna ati ina, O ran Jibril- ki ọla maa ba a- lọ sí alujanna, O wa sọ pé: Wò ó, ki o si wo ohun ti Mo pèsè kalẹ̀ fun awọn ọmọ alujanna ninu rẹ. Ni o ba wo o, o si ṣẹri pada, ni o wa sọ pe: Mo fi agbara Rẹ bura, ko si ẹni kankan ti o maa gbọ nipa rẹ ti ko nii wọ̀ ọ́. Ni O ba pàṣẹ ki wọn fi àwọn nǹkan ti ẹmi korira rọkirika rẹ, O wa sọ pé: Tún lọ sibẹ, ki o si wo o ati ohun ti Mo pèsè kalẹ̀ fún àwọn ọmọ alujanna nínú rẹ̀. Ni o wa wo o, o si ba a pe wọn ti fi àwọn ohun tí ẹ̀mí korira rọkirika rẹ, o wa sọ pé: Mo fi agbara Rẹ bura, ẹ̀rù n ba mi ki ẹni kankan ma wọ ibẹ̀. O sọ pé: Lọ wo ina ati ohun ti Mo pèsè kalẹ fun awọn ọmọ ina nínú ẹ. O wo inu rẹ, ni o wa ri i ti o n gun ara wọn, o ṣẹri pada, o si sọ pé: Mo fi agbara Rẹ bura, ko si ẹni kankan ti o maa wọ̀ ọ́. Ni O wa ni ki wọn fi àwọn nǹkan ti ẹmi maa n gbádùn rọkirika rẹ, o padà, o si sọ pé: Mo fi agbara Rẹ bura, mo n paya ki ẹni kankan má là kúrò nibẹ ayafi ki o wọ̀ ọ́”.

[O daa] [Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun, nigba ti O da alujanna ati ina, O sọ fun Jibril- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- pé: Lọ si alujanna ki o si wo o, bayii ni o ṣe lọ, o si wo o, lẹyin naa o ṣẹri pada, Jubril si sọ pé: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa rẹ ati nipa nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu idẹra ati awọn oore afi ko fẹ lati wọ ọ, ki o si maa ṣe iṣẹ́ nitori rẹ. Lẹyin naa Ọlọhun wa fi awọn nnkan ti ẹmi korira ati awọn nǹkan ti ó le rọkirika alujanna bii ṣíṣe awọn nnkan ti wọn pa wa láṣẹ ati jijina si awọn nnkan ti wọn kọ̀; o wa jẹ dandan fun ẹni ti o ba fẹ wọ ọ lati re kọja awọn nnkan ti ẹmi korira yẹn. Lẹyin naa Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- sọ pé: Irẹ Jibril! Lọ ki o lọ wo alujanna, lẹyin igba ti O rọkirika rẹ pẹlu awọn nnkan ti ènìyàn korira, O si lọ wo o, lẹyin naa o sọ pe: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura, mo n paya ki ẹnikẹni ma wọ ọ pẹlu okunfa awọn ilekoko ati awọn wahala ti wọn wa ni oju ọna rẹ. Nígbà ti Ọlọhun da ina, O sọ pe: Irẹ Jibril! Lọ ki o lọ wo o, o si lọ wo o, Lẹyin naa ni o dé, Jibril wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa iya ati awọn wahala ati ìfìyàjẹ ti o wa nínú rẹ̀ afi ki o korira lati wọ ọ ki o sì jina si awọn okunfa rẹ. Lẹyin naa Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- fi àwọn adùn rọkirika ina, O si ṣe wọn ni oju ọna lọ si ibẹ, lẹyin naa, O sọ pe: Irẹ Jibril, lọ ki o si wo o, Jibril si lọ o si wo o, lẹyin naa o de, o si sọ pe: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura, dajudaju mo paya ẹru si ba mi pe ki ẹni kankan ma la kuro nibẹ; fun nnkan ti o rọkirika rẹ ninu awọn adun.

فوائد الحديث

Nini igbagbọ pe alujanna ati ina n bẹ báyìí.

Jijẹ dandan nini igbagbọ ninu kọ̀kọ̀ ati gbogbo nnkan ti o wa lati ọdọ Ọlọhun ati lati ọdọ Ojiṣẹ Rẹ (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a).

Pataki ṣíṣe suuru lori awọn nnkan ti ènìyàn korira; nitori pe àwọn ni oju ọna ti o de alujanna.

Pataki jijina si awọn nnkan eewọ; nitori pe àwọn ni oju ọna ti o de ina.

O ṣe alujanna ni nnkan ti wọn fi àwọn nǹkan ti ẹmi korira rọkirika, O si ṣe ina ni nǹkan ti wọn fi àwọn adùn rọkirika, oun ni nǹkan ti ìdánwò isẹmi ayé n béèrè fun.

Oju ọna alujanna ṣoro o si le, o si bukaata si ṣíṣe suuru ati atẹmọra pẹlu igbagbọ, ati pe oju ọna ina kun fun adun ni aye.

التصنيفات

Nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin., Awọn iroyin alujanna