Ti ẹ ba ti fẹ kirun, ẹ gbe saafu yin dìde, lẹyin naa ki ẹnikan ninu yin ṣe imaamu fun yín, ti o ba ti kabara, ki ẹyin naa kabara

Ti ẹ ba ti fẹ kirun, ẹ gbe saafu yin dìde, lẹyin naa ki ẹnikan ninu yin ṣe imaamu fun yín, ti o ba ti kabara, ki ẹyin naa kabara

Lati ọdọ Hitton ọmọ Abdullahi Ar-Roqooshiy o sọ pe: Mo kirun kan pẹlu Abu Musa Al-Ash'ariy, nigba ti o wa lori ìjókòó, arakunrin kan ninu ijọ sọ pe: Wọn ti da irun pọ mọ ṣíṣe daadaa ati saka, o sọ pe: Nigba ti Abu Musa kirun tan ti o si salamọ, o kọ ju sẹ́yìn, ni o wa sọ pe: Ewo ninu yin lo sọ gbolohun bayii bayii? O sọ pe: Ni awọn èèyàn ba dakẹ, lẹyin naa o sọ pe: Ewo ninu yin lo sọ gbolohun bayii bayii? Ni awọn èèyàn ba dakẹ, o sọ pe: Boya iwọ Hitton lo sọ ọ? O sọ pe: Mi ko sọ ọ, mo bẹru pe ki o ma bu mi nitori rẹ, arakunrin kan ninu wa sọ pe: Emi ni mo sọ ọ, mi ko si gbero nnkan kan pẹlu rẹ afi dáadáa, ni Abu Musa wa sọ pe: Ṣe ẹ ko mọ bi ẹ ṣe ma maa sọ nibi irun yin ni? Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọ̀rọ̀ ti o si ṣàlàyé sunnah wa fun wa ti o si kọ wa ni irun wa, o wa sọ pe: "Ti ẹ ba ti fẹ kirun, ẹ gbe saafu yin dìde, lẹyin naa ki ẹnikan ninu yin ṣe imaamu fun yín, ti o ba ti kabara, ki ẹyin naa kabara, ti o ba sọ pe: (Ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen) (Al- Fatiha: 7), ki ẹ sọ pé: Aamiin, Ọlọhun maa da yin lóhùn, ti o ba ti kabara ti o si rukuu, ki ẹyin naa kabara ki ẹ si rukuu, dajudaju imaamu maa rukuu ṣíwájú yín, yio si gbe ori dide ṣíwájú yín", ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: "Iyẹn pẹlu ìyẹn, ti o ba sọ pe: Sami'alloohu liman hamidaHu, ẹ sọ pé: Allahumo Robbanaa wa laKal hamd, Ọlọhun maa gbọ́ yín, dajudaju Ọlọhun- ibukun ni fun orúkọ Rẹ, ti ọla Rẹ ga- sọ lori ahọn Anabi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Sami'alloohu liman hamidaHu, ti o ba ti kabara ti o forikanlẹ, ki ẹyin naa kabara ki ẹ si forikanlẹ, dájúdájú imaamu maa forikanlẹ ṣíwájú yín, o si maa gbe ori dide ṣíwájú yín", ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pe: "Iyẹn pẹlu ìyẹn, ti o ba ti wa lori ìjókòó, ki ọrọ akọkọ ẹni kọọkan ninu yin jẹ: At-tahiyyatu t-tayyibaatus-salawaatu lillah, as-salamu ‘alayka ayyuha’n-Nabiyyu wa rahmatulLaahi wa barakatuhu, as-salamu ‘alayna wa alaa ibaadil Laahis sọọlihiin, ash'hadu an laa ilaaha illal Loohu wa ash'hadu anna Muhammadan abduhuu wa rọsuuluhuu".

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Saabe ti o n jẹ Abu Musa Al-Ash'ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- kirun kan, nigba ti o wa ni ijokoo ti ataya wa nibẹ, arakunrin kan ninu awọn ti wọn kirun lẹyin rẹ sọ pe: Wọn da irun pọ mọ daadaa ati saka ninu Kuraani, nigba ti Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- kirun tan, o doju kọ awọn ero ẹyin, ni o wa bi wọn leere pé: Ewo ninu yin lo sọ gbolohun: Wọn da irun pọ mọ daadaa ati saka ninu Kuraani?! Ni awọn èèyàn ba dakẹ, ti ẹnikẹni ko sọ̀rọ̀ ninu wọn, ni o ba paara ibeere naa lẹẹkan si, nigba ti ẹnikẹni ko da a lohun, Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe: Boya iwọ Hittọọn ni o sọ ọ! Nitori ìgboyà rẹ ati asunmọ rẹ ati asopọ rẹ pẹlu rẹ, ninu nnkan ti kikẹfin rẹ ko lee ko suta ba a, ati pe ki o le ti ẹni ti o ṣe e gangan jade lati jẹwọ, ni Hittọọn wa sọ pe ko ri bẹ́ẹ̀, o wa sọ pe: Mo bẹru ki o ma bu mi ti o n lero pe emi ni mo sọ ọ; ibi yii ni arakunrin kan ti sọ ninu awọn ijọ pe: Emi ni mo sọ ọ, mi ko si gbero nnkan kan pẹlu rẹ afi dáadáa, ni Abu Musa wa sọ ni ẹni ti o n kọ ọ pé: Ṣe ẹ ko mọ bi ẹ ṣe ma maa sọ lori irun yin ni?! Eleyii jẹ àtakò lati ọdọ rẹ, lẹyin naa Abu Musa wa sọ pe dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba awọn sọ̀rọ̀ ni ọjọ kan, ti o ṣàlàyé Sharia wọn fun wọn, ti o kọ wọn ni irun wọn, ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Ti ẹ ba fẹ kirun, ki ẹ ya gbe saafu dide ki ẹ si duro tọ́ nibẹ, lẹyin naa ki ẹnikan ninu wọn ṣe imaamu fun awọn eniyan, ti imaamu ba ti kabara wiwọ inu irun, ki ẹyin naa kabara iru rẹ, ti o ba ti ka Fatiha ti o ba wa de: ((Ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen) (Al- Fatiha: 7)), ki ẹ sọ pe: Aamiin; ti ẹ ba ṣe bẹẹ Ọlọhun maa gba adura yin, ti o ba kabara ti o si rukuu, ki ẹyin naa kabara ki ẹ si rukuu; dajudaju imaamu maa rukuu ṣíwájú yín o si maa gbe ori dide ṣíwájú yín, nitori naa ẹ ko gbọdọ ṣíwájú rẹ; nitori pe asiko ti imaamu gba waju nibẹ lati ṣíwájú yin rukuu, ilọra yin ni rukuu lẹyin ti imaamu ti gbori kuro maa di i fun yin, iru asiko yẹn pẹlu asiko yẹn, odiwọn rukuu yin maa da gẹgẹ bii odiwọn rukuu rẹ, ti imaamu ba sọ pe: Sami'alloohu liman hamidaHu, ki ẹ sọ pé: Allahumo Robbanaa wa laKal hamdu, ti awọn ero ẹyin ba sọ ìyẹn, dajudaju Ọlọhun- mimọ ni fun Un- maa gbọ́ adura wọn ati ọrọ wọn, nitori pe Ọlọhun- ibukun ni fun orúkọ Rẹ, ti ọla Rẹ ga- sọ lori ahọn Anabi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Samihal Loohu liman hamidaHu, lẹyin naa ti imaamu ba kabara ti o si forikanlẹ, o jẹ dandan fun awọn ero ẹyin lati kabara ki wọn si forikanlẹ, dajudaju imaamu maa forikanlẹ ṣíwájú wọn, o si maa gbe ori dide ṣíwájú wọn, iru asiko yẹn pẹlu asiko yẹn, odiwọn iforikanlẹ ero ẹyin maa da gẹgẹ bii odiwọn iforikanlẹ imaamu, ti o ba wa lori ijokoo ataya, ki akọkọ ọrọ olukirun jẹ: At-tahiyyaatu toyyibaatus solawaatu lillah" Ọla ati ṣiṣẹku ati titobi gbogbo rẹ pata jẹ ẹtọ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, gẹgẹ bẹ́ẹ̀ naa ni awọn irun maraarun-un, gbogbo rẹ pata jẹ ti Ọlọhun, "As-salaamu 'alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu, as-salaamu 'alayna wa 'alaa 'ibaadillahis soliheen", ẹ pe Ọlọhun fun lila kuro nibi gbogbo aleebu ati adinku ati ibajẹ; a maa ṣẹsa Anabi wa Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu àlàáfíà, lẹyin naa a maa tọrọ alaafia fun ara wa, lẹyin naa a maa tọrọ alaafia fun awọn ẹru Ọlọhun ti wọn jẹ ẹni rere ti wọn ṣe nnkan ti o jẹ dandan fun wọn ninu awọn iwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati awọn iwọ awọn ẹru Rẹ, lẹyin naa, a maa jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si lododo afi Ọlọhun, a si n jẹrii pe dajudaju Muhammad ẹru Rẹ ni ati ojiṣẹ Rẹ.

فوائد الحديث

Ṣíṣe alaye àwòrán kan ninu awọn àwòrán bi gbólóhùn ataaya ṣe wa.

Awọn iṣẹ ori irun ati awọn ọrọ rẹ, ko gbọdọ ma jẹ nnkan ti o fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ko lẹtọọ fun ẹnikẹni lati da adadaalẹ silẹ nibẹ ni ti ọrọ ati iṣẹ ti ko fi ẹsẹ rinlẹ ninu sunnah.

Ailẹtọọ ṣíṣíwájú imam ati lilọra lẹyin rẹ, ati pe nnkan ti a ṣe lofin fun ero ẹyin ni itẹle imam nibi awọn iṣe rẹ.

Sísọ nnkan ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa lori rẹ ninu akolekan imude-etigbọọ awọn eniyan, ati kikọ ìjọ rẹ ni awọn idajọ ẹsin.

Imam ni awokọṣe fun ero ẹyin, ko lẹtọọ lati ṣíwájú rẹ nibi awọn iṣẹ ori irun, tabi lati ṣe deedee rẹ tabi lati lọra lẹyin rẹ, bi ko ṣe pe ki ìbẹ̀rẹ̀ itẹle rẹ jẹ lẹyin aridaju wiwọle rẹ sinu iṣẹ ti o fẹ ṣe, ati pe sunnah ni titẹle rẹ nibẹ.

Ṣiṣe gbigbe saafu dide lofin nibi irun.

التصنيفات

Iroyin irun, Awọn idajọ imam ati ero ẹyin