“Awọn ẹṣẹ nlanla ni: Mimu orogun pẹlu Ọlọhun, ṣiṣẹ baba ati ìyá, pipa ẹmi, ati bibura lori irọ”

“Awọn ẹṣẹ nlanla ni: Mimu orogun pẹlu Ọlọhun, ṣiṣẹ baba ati ìyá, pipa ẹmi, ati bibura lori irọ”

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Awọn ẹṣẹ nlanla ni: Mimu orogun pẹlu Ọlọhun, ṣiṣẹ baba ati ìyá, pipa ẹmi, ati bibura lori irọ”.

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe awọn nlanla ninu awọn ẹṣẹ, àwọn ni eyi ti wọn ṣe adehun iya fun ẹni ti o ba ṣe e pẹlu adehun iya ti o le koko ni aye tabi ni ọrun. Akọkọ ninu ẹ ni “Mimu orogun pọ mọ Ọlọhun”: Oun ni yiyi eyikeyii iran ninu awọn iran ijọsin fun ẹni ti o yatọ si Ọlọhun, ati gbigbe ẹni ti o yatọ si Ọlọhun si ipo Ọlọhun nibi nnkan ti o jẹ awọn ẹsa Ọlọhun nibi ìní-ẹ̀tọ́ si ijọsin Rẹ, ati nibi jijẹ Oluwa Rẹ ati nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ. Ikeji nibẹ ni “Ṣiṣẹ baba ati iya”: Oun ni gbogbo nnkan ti o le sọ fifi suta kan baba ati iya di dandan ni ti ọrọ ni tabi iṣe, ati gbigbe ṣiṣe daadaa si wọn ju silẹ. Ikẹta nibẹ ni “pipa ẹmi”: Laini ẹtọ, gẹgẹ bii pipa ẹmi ni ti abosi ati ni ti itayọ ẹnu-àlà. Ikẹrin nibẹ ni “Bibura lori irọ”: Oun ni bibura ni ẹni tí n pa irọ ti o si mọ̀ pé irọ́ ni oun n pa, wọn sọ ọ ni orúkọ yẹn; nitori pe o maa n tẹ ẹni ti o n pa a ri sinu ẹṣẹ tabi inu ina.

فوائد الحديث

Bibura lori irọ, ko si ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ fun un; nitori lile koko ewu rẹ ati ẹṣẹ rẹ, bi ko ṣe pe ironupiwada ni o wa nibẹ.

Wọn dárúkọ awọn ẹṣẹ nlanla mẹrin yii nìkan ninu hadiisi naa fun titobi ẹṣẹ wọn, kii ṣe pe àwọn nìkan naa ni ẹ̀ṣẹ̀ ńláǹlà.

Awọn ẹṣẹ pin si nlanla ati keekeeke, awọn nlanla ni: Gbogbo ẹṣẹ ti ijiya ti aye n bẹ nibẹ, gẹgẹ bii ijiya ti sharia fi ààlà si, ati ègún, tabi adehun iya ti ọrun, gẹgẹ bii adehun iya pẹlu wiwọ ina, ati pe awọn ẹṣẹ nlanla ìpele ìpele ni wọn, awọn kan ninu wọn nipọn ju awọn kan lọ nibi jijẹ eewọ, awọn ẹṣẹ keekeeke ni awọn ti wọn yatọ si awọn ẹṣẹ ńláńlá.

التصنيفات

Aleebu awọn ẹṣẹ