Oluran awọn opo ati alaini lọwọ, da gẹgẹ bii olugbinyanju soju ọna Ọlọhun, tabi ẹni ti o n fi oru rẹ dide ti o si n fi ọsan rẹ gba awẹ

Oluran awọn opo ati alaini lọwọ, da gẹgẹ bii olugbinyanju soju ọna Ọlọhun, tabi ẹni ti o n fi oru rẹ dide ti o si n fi ọsan rẹ gba awẹ

Lati ọdọ Abu Huraira, o sọ pe: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Oluran awọn opo ati alaini lọwọ, da gẹgẹ bii olugbinyanju soju ọna Ọlọhun, tabi ẹni ti o n fi oru rẹ dide ti o si n fi ọsan rẹ gba awẹ".

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba n ṣe anfaani fun obinrin ti ọkọ rẹ ku, ti ko ni ẹni kankan ti o maa moju to awọn alamọri rẹ, ati alaini ti o ni bukaata, ti o si n na owo fun wọn ni ẹni ti o n wa ẹsan lọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nibi ẹsan, o da gẹgẹ bii olujagun loju ọna Ọlọhun, tabi ẹni ti o n ki irun ni oru ti ko ki n rẹ ẹ, ati alaawẹ ti ko ki n túnu.

فوائد الحديث

Ṣisẹnilojukokoro lori iran-ara-ẹni-lọwọ ati ikun-ara-ẹni-lọwọ ati didi bukaata awọn ọlẹ.

Ijọsin ko gbogbo iṣẹ oloore sínú, ati pe ninu ijọsin ni riran awọn opo ati alaini lọwọ wa.

Ibnu Hubairọ sọ pe: Nnkan ti a gba lero ni pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa ko ẹsan alaawẹ ati eni ti o n dide loru ati olujagun fun un lẹẹkan naa; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe o duro sipo ọkọ fun opo...., o si duro ti alaini yẹn ti ko lee da duro fun ara rẹ, eleyii si na nǹkan ti o le si nǹkan ti o bukaata si, o si ṣe saara pẹlu igbiyanju rẹ, nitori naa anfaani rẹ wa ṣe deedee awẹ ati didide ati igbiyanju soju ọna Ọlọhun.

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun awọn iṣẹ awọn orikerike ara