Alaye iwẹ latara janaba

Alaye iwẹ latara janaba

Lati ọdọ Maymūna iya gbogbo mumini - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbe omi iwẹ fun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - mo si fi aṣọ kan bo o, o wa da omi si ọwọ rẹ mejeeji, ti o si fọ wọn, lẹyin naa ni o fi ọwọ ọtun rẹ da omi si ọwọ osi, o si fọ abẹ rẹ, ni o wa fi ọwọ rẹ lu ilẹ, ti o si nu un, lẹyin naa ni o fọ ọ, ni o wa fi omi yọ ẹnu o si tun fin in si imu, o si tun fọ oju rẹ ati apa rẹ mejeeji, lẹyin naa ni o da omi si ori rẹ ti o si da a si ara rẹ, lẹyin naa ni o bọ́ sí ẹgbẹ kan, ti o si fọ ẹsẹ rẹ mejeeji, ni mo wa fun un ni aṣọ kan ti ko si gba a, ni o wa jade lẹni ti o n gbọn owo rẹ mejeeji.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Iya awọn olugbagbọ Maimuunah- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ nipa alaye iwẹ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- latara janaba, nigba ti o gbe omi fun un lati fi wẹ, ti o si da gaga kan bo o, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣe awọn nnkan ti o n bọ yìí: Akọkọ: O da omi si ọwọ rẹ mejeeji o si fọ mejeeji ṣíwájú ki o to ti mejeeji bọ inu igba. Ikeji: O da omi pẹlu ọwọ rẹ ọtun lori osi o si fọ abẹ rẹ; lati mọ ọn kuro nibi nnkan ti o ba lẹ̀ mọ́ ọn ninu oripa janaba. Ikẹta: O fi ọwọ rẹ lu ilẹ̀, o si nù ún, lẹ́yìn náà o fọ ọ lati le mu ẹgbin kuro nibẹ. Ikẹrin: O fi omi yọ ẹnu rẹ: pẹlu ki o fi omi si ẹnu rẹ, o si mi I, o yi i lẹyin naa o tu u, o fin omi simu; pẹlu ki o fi omi simu rẹ pẹlu èémí rẹ, lẹyin naa o mu u jade lati fi mọ ọn. Ikarun-un: O fọ oju rẹ ati awọn apa rẹ mejeeji. Ikẹfa: O da omi si ori rẹ. Ikeje: O da omi si awọn toku ninu ara rẹ. Ikẹjọ: O kuro nibi aaye rẹ o si fọ ẹsẹ rẹ mejeeji ní ibòmíì tí kò tíì fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Lẹyin naa, o mu aṣọ kan wa fun un lati nu ara rẹ pẹlu rẹ, ṣùgbọ́n ko gba a, o bẹ̀rẹ̀ si n nu omi kuro lara rẹ pẹlu ọwọ rẹ ti o si n gbọn ọn.

فوائد الحديث

Akolekan awọn iyawo Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu alaye kúlẹ̀kúlẹ̀ ti o kéré jù lọ ninu isẹmi aye rẹ; lati fi jẹ ẹkọ fun ijọ Anabi.

Alaye iwẹ yìí jẹ ọkan ninu awọn ọna ti o fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi bi a ṣe maa n wẹ iwẹ ti o pe latara janaba, ṣùgbọ́n ọna ti o to ni ki o fi omi kari ara rẹ pẹlu fifi omi yọ ẹnu ati fifin in simu.

Fifi aṣọ nu ara tabi fifi i silẹ lẹyin iwẹ tabi aluwala jẹ nnkan ti o tọ́.

التصنيفات

Iwẹ