O gba Isilaamu lori nnkan ti o ṣáájú ninu daadaa”

O gba Isilaamu lori nnkan ti o ṣáájú ninu daadaa”

Lati ọdọ Hakeem ọmọ Hizaam- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe: Mo sọ pé: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, fun mi ni iro nipa nnkan ti mo maa n se wọn ni asiko aimọkan bii saara ṣíṣe ati bibọkun kúrò lọrun ẹru ati dida ibi pọ, njẹ ẹsan wa nibẹ? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “O gba Isilaamu lori nnkan ti o ṣáájú ninu daadaa”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe alaigbagbọ ti o ba gba Isilaamu wọn maa san an lẹsan lori nnkan ti o n ṣe ni asiko aimọkan ṣíwájú gbigba Isilaamu rẹ ninu awọn iṣẹ oloore bii saara ṣíṣe ati bibọkun kúrò lọrun ẹru tabi siso ibi papọ.

فوائد الحديث

Dajudaju awọn daadaa ti alaigbagbọ ba ṣe wọn ko nii san an lẹsan lori wọn ni ọrun ti o ba ku lori ṣíṣe aigbagbọ rẹ.

التصنيفات

Ẹsin Isilaamu