إعدادات العرض
Mo wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni o wa lọ sibi akitan ijọ kan, ti o si tọ ni iduro,
Mo wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni o wa lọ sibi akitan ijọ kan, ti o si tọ ni iduro,
Lati ọdọ Hudhayfah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni o wa lọ sibi akitan ijọ kan, ti o si tọ ni iduro, ni mo ba takete si i, o wa sọ pe: «Sunmọ ibi» ni mo ba sunmọ titi mo fi duro si ibi ẹyin gigirisẹ rẹ mejeeji, nigba naa ni o ṣe aluwala ti o si fi ọwọ pa ibọsẹ alawọ rẹ mejeeji.
[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी සිංහල ئۇيغۇرچە Hausa Português Kurdî Kiswahili دری অসমীয়া ไทย Tiếng Việt አማርኛ Svenska Кыргызча ગુજરાતી नेपाली Oromoo Română മലയാളം Nederlands Soomaali پښتو తెలుగు Kinyarwanda ಕನ್ನಡ Malagasyالشرح
Hudhayfah ọmọ Al-yamān - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- n royin pe oun wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-, ni o wa gbero - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - lati tọ, ti o si wọ subāta ijọ kan; oun naa ni aaye ti wọn maa n da idọti ati iyẹpẹ ti wọn ba gba jade ni inu ile si, nigba naa ni o wa tọ ni iduro, èyí tí o si pọ ninu ìṣesí rẹ ni ki o tọ ni ijokoo. Ni Hudhayfah wa takete si i, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun un pe: Sunmọ ibi, ti Hudhayfah si sunmọ ọn titi ti o fi duro si ẹyin rẹ nibi gigisẹ rẹ mejeeji; ki o le wa gẹgẹ bii gaga fun un ki wọn ma baa ri i ni ìṣesí yẹn. Lẹyin naa ni o wa ṣe aluwala - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, nigba ti o de ibi fifọ ẹsẹ mejeeji, o fi mọ lórí pipa ibọsẹ alawọ rẹ mejeeji - awọn ni awọ fẹlẹfẹlẹ tabi nkan ti o jọ ọ ti wọn maa n bọ si ẹsẹ ti yio si bo koko ẹsẹ mejeeji - ti ko si bọ wọn silẹ.فوائد الحديث
Ṣiṣe lofin pipa ibọsẹ alawọ mejeeji.
Ìní-ẹ̀tọ́ titọ ni iduro pẹlu majẹmu ki nkankan ninu rẹ o ma ta si i lara.
Ṣiṣẹṣa ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣa As-Subāto lẹsa - oun naa ni aaye idalẹ ati idọti sí - latari pe ni ọpọ igba o maa rẹlẹ ko si ki n da itọ pada si ara ẹni ti o n tọ.