Ti ki báa ṣe pe kin má ko waala bá awọn olugbagbọ ododo ni - tabi awọn ijọ mi ni - mi o ba pa wọ́n laṣẹ lati máa rin pako ni gbogbo asiko Irun kọọkan

Ti ki báa ṣe pe kin má ko waala bá awọn olugbagbọ ododo ni - tabi awọn ijọ mi ni - mi o ba pa wọ́n laṣẹ lati máa rin pako ni gbogbo asiko Irun kọọkan

Lati ọdọ Abu Hurayrah - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ bayi pe: Ti ki báa ṣe pe kin má ko waala bá awọn olugbagbọ ododo ni - tabi awọn ijọ mi ni - mi o ba pa wọ́n laṣẹ lati máa rin pako ni gbogbo asiko Irun kọọkan.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Annabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a fún wa niro pe, ti ki baa ṣe ìbẹrù waala fún awọn olugbagbọ ododo ninu awọn ijọ rẹ̀, ko ba ṣe ni dandan fun wọn lati ma run pako ni gbogbo igba ti wọ́n ba fẹ kirun.

فوائد الحديث

Aanu ati iṣepẹlẹ Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - fún awọn ijọ rẹ, ati ifoya (ìbẹrù) waala (ìnira) fún àwọn ìjọ rẹ.

Ìpìlẹ ni pe ti Anọbi ba paṣe - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - yoo tumọn sí ọranyan (dandan) àyaàfi tí ẹrí mi ba wà ti o ntọkasi pe aṣegbọrẹ ni.

Fifẹ ti a fẹ ki a run pako ati ọlá rẹ̀ ni gbogbo asiko irun.

Ibn Daqeeq Al-hiid sọ bayi pe: ọgbọn ati oye ti o wa nibi fifẹ ki a run pako nigbati a ba fẹ lọ kirun, ohun ni pe wiwa ni asiko isunmọ Ọlọhun, ti nṣe idalẹjọ pé ki o jẹ iṣesi pipe ati imọtoto, lati le ṣe afihan pataki ìjọsìn.

Akotan (àpapọ) hadith náà ṣe akopọ rirun pako aláawẹ kódà bi o ṣe pé lẹyin ti oorun ti kan àtàrí, gégébí irun ọsan (sùúri) ati irun irọlẹ (Asri).

التصنيفات

Awọn iwa daadaa ti Anabi