إعدادات العرض
Mo sọ pé: Mope irẹ ojisẹ Ọlọhun kini ìgbàlà? O sọ pé: “ko ahán rẹ ni ijanu, jẹ kí ilé rẹ gba ọ laaye, ki o si máa sunkún lori awọn àsise rẹ
Mo sọ pé: Mope irẹ ojisẹ Ọlọhun kini ìgbàlà? O sọ pé: “ko ahán rẹ ni ijanu, jẹ kí ilé rẹ gba ọ laaye, ki o si máa sunkún lori awọn àsise rẹ
Lati ọdọ 'Uqbatu ọmọ 'Aamir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé: "Mo sọ pé: Mope irẹ ojisẹ Ọlọhun kini ìgbàlà? O sọ pé: “ko ahán rẹ ni ijanu, jẹ kí ilé rẹ gba ọ laaye, ki o si máa sunkún lori awọn àsise rẹ".
[O ni alaafia] [Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa]
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी සිංහල ئۇيغۇرچە Hausa Kurdî Kiswahili Português Nederlands Tiếng Việt অসমীয়া ગુજરાતી پښتو മലയാളം नेपाली ქართული Magyar తెలుగు Македонски Svenska ಕನ್ನಡ Moore Română Українська ไทย मराठी ਪੰਜਾਬੀ دری አማርኛ Wolof ភាសាខ្មែរ Malagasy Српскиالشرح
'Uqbatu ọmọ 'Aamir ki Ọlọhun yọnu si beere lọwọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nipa Òkùnfà ti olugbàgbọ òdodo yóò fi ri àkóyọ láyé ati lọrun? Ni ojisẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Rẹ máa ba) wa sọ pé: nkan mẹta di ọwọ rẹ: Èkíní: ṣọ ahán rẹ kúrò níbi nkan ti kosi oore nibẹ, ati kúrò níbi gbogbo ọrọ aburu, ma se sọ ọrọ kan afi ko jẹ ọrọ daada. Ikeji: fìdí rẹ mọ ile rẹ ki o lè máa ṣe ìjọsìn fún Ọlọhun ni kọkọ (nigbati o ba da wa), gbaju mọ itẹle aṣẹ Ọlọhun Ọba to gbọngbọn ti o tun ga jùlọ, dáwà ninu ile rẹ lati sa fún wahala. Ikẹta: Máa sunkún ki o si máa ṣe àbámọ ki o si tuuba (tọrọ aforinjin ati iyọwọ kúrò) ni bi awọn ẹsẹ ti o ti ṣe kọja.فوائد الحديث
Ojúkòkòrò ati inifẹ awọn saabe (awọn ọmọ leyin Anọbi, awọn musulumi akọkọ) ki Ọlọhun yonu si wọn, inifẹ wọn sí mímọ awọn ọna ìgbàlà tabi àkóyọ.
Alaye nipa awọn okunfa àkóyọ láyé ati lọrun.
Iṣeni lojúkòkòrò lori ki eniyan mu ọrọ ara rẹ gbọ nigbati o ba kágara lati wúlò fún ẹlòmíràn, tabi tiba nbẹru ìnira lori ẹṣin ati emi rẹ nígbàtí o ba ro papọ mọ awọn eniyan .
Itọkasi sise akakun ile pataki jùlọ nigbati wahala ba nṣẹlẹ, ohun ni ọna ti a le fi dáa bo bo ẹsin.