“Irun ọkunrin kan pẹ̀lú janmọọn ju irun rẹ nile lọ ati Irun rẹ ni ọja lọ pẹlu ipò ogún lé ní nǹkan kan

“Irun ọkunrin kan pẹ̀lú janmọọn ju irun rẹ nile lọ ati Irun rẹ ni ọja lọ pẹlu ipò ogún lé ní nǹkan kan

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: “Irun ọkunrin kan pẹ̀lú janmọọn ju irun rẹ nile lọ ati Irun rẹ ni ọja lọ pẹlu ipò ogún lé ní nǹkan kan. nitori pe ti ẹnìkan ninu wọn ba ṣe aluwala daadaa, lẹ́yìn naa o wa lọ sí mọ́sálásí, ko si nkankan ti o gbe e dide ayafi irun, ko si gbero nǹkan kan ayafi irun, nitori naa ko nii gbe ẹsẹ kan àyàfi ki Ọlọhun fi ṣe agbega fun un, ati ki O fi pa asiṣe rẹ rẹ́, titi ti yio fi wọ masalasi. Ti o ba ti wa wọ mọ́sálásí, o ti wa lori irun lópin igba ti o ba jẹ pe irun ni o n da a dúró, àwọn Malaika si ma maa ṣe adura fun ẹni kọọkan ninu yin ni iwọn igba ti o ba ṣi wa lori ijokoo ti o ti kirun, wọn maa sọ pe: Ọlọhun, ṣãnu fun un, Ọlọrun, dari jin in, Ọlọrun, gba ironupiwada rẹ, ni iwọn igba ti ko ba ti ṣe ipalara nibẹ, ti ko si ṣe ẹgbin nibẹ".

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- sọ fun wa wí pé ti musulumi ba ki Irun ni janmọọn, Irun rẹ ni ọla ju Irun rẹ ni ile tabi ni ọja lọ ni ọ̀nà igba ti o le ni ogún. Lẹ́yìn naa ni o sọ okùnfà ìyẹn: Oun naa ni pé ti ọkùnrin kan ba ṣe aluwala ti o si pari aluwala naa ti o si ṣe e daadaa, ti o wa jade lọ si mọ́sálásí, ti ko si si ohun ti o gbe e jade ayafi ìrun, ko nii gbe ẹsẹ kan àyàfi ki wọn ṣe ipo to ga ati aaye to ga fun un, ki wọn si tun fi pa àṣìṣe rẹ rẹ. Ti eniyan ba wọ inu mọṣalaṣi ti o si jokoo ti o n duro fun Irun, yìo gba ẹ̀san Irun lopin ìgbà tí ó bá ṣi n retí irun, àwọn Malaika a maa se adua fun un, ni igba ti o ba wa ni ori ìjókòó ti o ti kirun, wọn maa sọ pe: Ọlọhun, dárí jin in, Ọlọhun, ṣãnu fun un, Ọlọrun, gba ironupiwada rẹ,” , lopin ìgbà tí aluwala rẹ ko ba i tii bajẹ, ti ko si ṣe ipalara fun eniyan tabi awọn angẹli.

فوائد الحديث

Irun enikan nínú ilé tàbí ní ọjà, ó ni alaafia; ṣùgbọ́n o maa gba ẹṣẹ fun pe o gbe irun janmọọn ju silẹ láìní àwíjàre kankan.

Irun janmọọn nínú mọ́sálásí ju irun adaki lọ pẹlu ẹsan mẹẹdọgbọn, tabi mẹrindinlọgbọn, tabi mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.

Ọkan ninu awọn iṣẹ ti awọn angẹli ni adua siṣe fun awọn onigbagbọ.

Ọla lilọ sí mọ́sálásí ni ẹni tí o ni aluwala.

التصنيفات

Ọla ti o n bẹ fun irun janmọ ati awọn idajọ rẹ