“Mi o fi fitina kan kan sílẹ̀ lẹyin mi ti o ni àwọn ọkùnrin lara ju àwọn obìnrin lọ”

“Mi o fi fitina kan kan sílẹ̀ lẹyin mi ti o ni àwọn ọkùnrin lara ju àwọn obìnrin lọ”

Láti ọ̀dọ̀ Usaamah ọmọ Zayd- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Mi o fi fitina kan kan sílẹ̀ lẹyin mi ti o ni àwọn ọkùnrin lara ju àwọn obìnrin lọ”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe oun ko fi àdánwò kan kan silẹ lẹ́yìn oun ti o ni àwọn ọkùnrin lára ju àwọn obìnrin lọ, ti o ba jẹ ọkan ninu awọn araale rẹ ni, o le ṣẹlẹ̀ lati ọdọ rẹ nibi iyapa sharia lati tẹle e, ti o ba si jẹ àjòjì si i, o le ṣẹlẹ̀ pẹlu iropọ mọ́ ọn ati dida wà pẹ̀lú rẹ, ati aburu ti o le ti ibẹ jáde.

فوائد الحديث

Musulumi gbọdọ ṣọ́ra kúrò nibi fitina obìnrin, ki o si di gbogbo ọ̀nà ti o ba le mu u ko adanwo latara rẹ̀.

O tọ́ fun onigbagbọ ododo ki o dìrọ̀ mọ́ Ọlọhun, ki o si maa ṣe ojúkòkòrò lọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ lati la kúrò nibi awọn fitina.

التصنيفات

Aleebu ifẹ inu ati awọn adun aye