”Eyi ti o lẹtọọ julọ ninu awọn majẹmu lati mu ṣẹ ni nnkan ti ẹ fi sọ awọn abẹ di ẹtọ”

”Eyi ti o lẹtọọ julọ ninu awọn majẹmu lati mu ṣẹ ni nnkan ti ẹ fi sọ awọn abẹ di ẹtọ”

Lati ọdọ ‘Uqbah ọmọ ‘Aamir- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: ”Eyi ti o lẹtọọ julọ ninu awọn majẹmu lati mu ṣẹ ni nnkan ti ẹ fi sọ awọn abẹ di ẹtọ”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju eyi ti o lẹtọọ julọ ninu awọn majẹmu lati mú ṣẹ ni nnkan ti o jẹ okunfa nibi sisọ igbadun pẹlu obinrin di ẹtọ, awọn ni awọn majẹmu ti o lẹtọọ ti iyawo maa n beere fun wọn nibi siso yigi.

فوائد الحديث

Jijẹ dandan mimu awọn majẹmu ṣẹ ti ọkan ninu ọkọ ati iyawo ṣe ni dandan fun ara wọn, afi majẹmu kan ti o ṣe ẹtọ ni eewọ tabi ṣe eewọ lẹtọọ.

Mimu awọn majẹmu yigi ṣẹ jẹ nnkan ti o kanpa ju nnkan ti o yatọ si wọn lọ; nitori pe o jẹ ìjìrọ̀ fun sisọ awọn abẹ di ẹtọ.

Titobi ipo igbeyawo ninu Isilaamu, latari bi o ṣe kanpá mọ́ mimu awọn majẹmu rẹ ṣẹ.

التصنيفات

‏Awọn majẹmu nibi igbeyawo