إعدادات العرض
“Dajudaju Ọlọhun maa n fẹ́ lati mu awọn ofin idẹkun Rẹ wa, gẹgẹ bi O ṣe nífẹ̀ẹ́ lati mu awọn eyi ti o jẹ dandan wa”
“Dajudaju Ọlọhun maa n fẹ́ lati mu awọn ofin idẹkun Rẹ wa, gẹgẹ bi O ṣe nífẹ̀ẹ́ lati mu awọn eyi ti o jẹ dandan wa”
Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojisẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju Ọlọhun maa n fẹ́ lati mu awọn ofin idẹkun Rẹ wa, gẹgẹ bi O ṣe nífẹ̀ẹ́ lati mu awọn eyi ti o jẹ dandan wa”.
[O ni alaafia] [Ibnu Hibbaan ni o gba a wa]
الترجمة
العربية English မြန်မာ Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands اردو Español Bahasa Indonesia ئۇيغۇرچە বাংলা Türkçe Bosanski සිංහල हिन्दी Tiếng Việt Hausa മലയാളം తెలుగు Kiswahili ไทย پښتو অসমীয়া Shqip دری Ελληνικά Български Fulfulde Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių Malagasy or Română Kinyarwanda Српски тоҷикӣ O‘zbek नेपाली Moore Kurdî Oromoo Wolof Soomaali Français Tagalog Azərbaycan Українська bm தமிழ் Deutsch ქართული Português Македонски Magyar فارسی Русский 中文الشرح
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: Dajudaju Ọlọhun maa n nífẹ̀ẹ́ sí mímú awọn ofin idẹkun Rẹ ti O ṣe wọn lofin wa, ninu awọn nnkan ti O ṣe wọn ni fifuyẹ nibi awọn idajọ ati ijọsin, ati ṣíṣe irọrun nibẹ fun awọn ẹni ti a la iwọ Ọlọhun bọ lọrun fun idi kan- gẹgẹ bii dindin irun ku ati dida a pọ ni ori irin ajo-, Gẹgẹ bi O ṣe nífẹ̀ẹ́ si mimu awọn ofin ti wọn jẹ dandan wa, ninu awọn alamọri ti wọn jẹ dandan; nitori pe aṣẹ Ọlọhun nibi awọn ìdẹkùn ati awọn nnkan ti wọn jẹ dandan jẹ ọ̀kan.فوائد الحديث
Ikẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lori awọn ẹru Rẹ, ati pe Ọlọhun- mimọ ni fun Un- nífẹ̀ẹ́ si mimu nnkan ti o ba ṣe lofin wa ninu awọn idẹkun.
Pipe ofin sharia yii, ati gbigbe ìdààmú rẹ kuro fun Musulumi.