Aye o nii parẹ titi ti igba o fi sunmọ ara wọn

Aye o nii parẹ titi ti igba o fi sunmọ ara wọn

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Aye o nii parẹ titi ti igba o fi sunmọ ara wọn, ti ọdún o waa da bi oṣu, ti oṣu o da bii jimọ (ọsẹ), ti jimọ o da bii ọjọ, ti ọjọ o da bii wakati, ti wakati o waa da bii sísun ewe igi dabinu».

[O ni alaafia] [Ahmad ni o gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n funni niroo pe dajudaju ninu awọn ami opin aye ni sisunmọra igba, Ti ọdún si maa rekọja gẹgẹ bi oṣu ṣe n rekọja, Ati pe oṣu maa rekọja gẹgẹ bi ọsẹ ṣe n rekọja, Ati pe jimọ (ọsẹ) maa rekọja gẹgẹ bi ọjọ kan ṣe n rekọja, Ati pe ọjọ maa rekọja gẹgẹ bi wakati kan ṣe n rekọja, Ati pe wakati maa rekọja ni iyara ti o lagbara gẹgẹ bi wọn ṣe maa n jo ewé igi dabinu.

فوائد الحديث

Ninu awọn àmì igbẹyin aye ni yiyọ alubarika kuro ninu igba ati yiyara rẹ (igba).

التصنيفات

Isẹmi inu sàréè