“Dajudaju Ọlọhun maa ya arákùnrin kan sọ́tọ̀ nínú ìjọ mi lójú àwọn ẹ̀dá ni ọjọ́ igbende alukiyaamọ

“Dajudaju Ọlọhun maa ya arákùnrin kan sọ́tọ̀ nínú ìjọ mi lójú àwọn ẹ̀dá ni ọjọ́ igbende alukiyaamọ

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju Ọlọhun maa ya arákùnrin kan sọ́tọ̀ nínú ìjọ mi lójú àwọn ẹ̀dá ni ọjọ́ igbende alukiyaamọ, O maa ṣí ìwé iṣẹ mọkandinlọgọrun-un fun un, ìwé kọ̀ọ̀kan gùn ni odiwọn ibi tí ojú bá le rína dé, lẹyin naa O maa sọ pé: Ǹjẹ́ nǹkan kan n bẹ nínú eyi ti o fẹ takò? Ǹjẹ́ àwọn malaika òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá ti wọn jẹ oluṣọ ṣe àbòsí rẹ bi? O maa sọ pé: Rara, Irẹ Olúwa mi, O maa sọ pé: Ǹjẹ́ o ni àwíjàre kankan bi? O maa sọ pé: Rárá, Irẹ Oluwa mi, O maa sọ pé: Ko ri bẹẹ, dájúdájú o ni iṣẹ rere kan ni ọdọ Wa; torí pé ko si àbòsí fun ẹ ni oni, wọn maa wa mu iwe pélébé kan jáde ti ohun ti o wa ninu rẹ jẹ: ASH’HADU AN LAA ILAAHA ILLALLOHU, WA ASH’HADU ANNA MUHAMMADAN ABDUHUU WA ROSUULUHUU, O maa sọ pé: Mu òṣùwọ̀n rẹ wá, o maa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, iwe pélébé wo ni o wa pẹ̀lú àwọn ìwé iṣẹ yii? O maa sọ pé: Wọn ko nii ṣe abosi fun ọ, o sọ pe: Wọn maa gbe àwọn ìwé iṣẹ naa sórí abọ́ òṣùwọ̀n kan, wọn si maa fi iwe pélébé naa sórí abọ́ òṣùwọ̀n mii, ni àwọn iwe iṣẹ naa maa di ohun ti o fúyẹ́, ti iwe pélébé naa si maa wúwo, ko si nnkan kan ti o le wuwo ju orúkọ Ọlọhun lọ”.

[O ni alaafia] [Tirmiziy ni o gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun maa ṣẹsa arakunrin kan ninu ijọ rẹ lójú awọn ẹda ni ọjọ igbedide, wọn maa pe e lati ṣe ìṣirò iṣẹ fun un, O si maa fi iwe àkọsílẹ̀ mọkandinlọgọrun-un han an, àwọn naa ni awọn iwe awọn iṣẹ aburu rẹ ti o n ṣe ni aye, ati pe òró iwe àkọsílẹ̀ kọọkan gùn ni ìwọ̀n ibi tí irina ba dé, Lẹyin naa Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ fun arakunrin naa pe: Njẹ waa tako nnkankan ninu nnkan ti wọn kọ sinu awọn iwe àkọsílẹ̀ yii? Njẹ awọn Mọlaika mi Olùṣọ́ Olukọwe ṣe abosi rẹ? Arakunrin naa maa sọ pé: Rara Oluwa mi. Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ pé: Njẹ awijare n bẹ fun ẹ ninu nnkan ti o ti siwaju ninu awọn iṣẹ ni aye? Bóyá o jẹ igbagbe tabi àṣìṣe tabi aimọkan, Arakunrin naa maa sọ pé: Rara Oluwa mi, mi ko ni awijare kankan. Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ pé: Bẹẹ kọ, dajudaju daadaa kan n bẹ fun ẹ lọdọ wa, ati pe ko si abosi kan fun ẹ lónìí. O sọ pe: Yoo mu kaadi kan jade ti wọn kọ sibẹ pé: Mo n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si ni ododo afi Allahu, mo si n jẹrii pe Muhammad ẹrusin Ọlọhun ni ati Ojiṣẹ Rẹ. Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ fun arakunrin yii pé: Mú òṣùwọ̀n rẹ wa. Arakunrin naa maa sọ ni ẹni ti o n ṣe eemọ pé: Irẹ Oluwa mi! Ki ni òṣùwọ̀n kaadi yii já mọ́ ni ẹ̀gbẹ́ awọn iwe àkọsílẹ̀ yii? Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ pé: Abosi ko lee ṣẹlẹ̀ si ẹ lailai. O sọ pe: Wọn yoo gbe awọn iwe àkọsílẹ̀ naa sinu abọ́ òṣùwọ̀n kan, ati kaadi naa sinu abọ́ òṣùwọ̀n kan; bayii ni abọ́ òṣùwọ̀n ti awọn iwe àkọsílẹ̀ wa nibẹ maa di ohun ti o fuyẹ, ti abọ́ òṣùwọ̀n ti kaadi wa ninu rẹ maa tẹṣuwọn ti o maa wuwo, ni Ọlọhun ba maa fi ori jin in.

فوائد الحديث

Titobi gbolohun imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo: Jijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si ni ododo afi Allahu, ati wiwuwo rẹ ninu òṣùwọ̀n.

Sisọ gbolohun: Laa ilaaha illallohu ko tó pẹlu ahọn nikan, bi ko ṣe pe nini imọ nípa ìtumọ̀ rẹ ati ṣíṣe iṣẹ pẹlu nnkan ti o n bèèrè fun jẹ dandan.

Imọkanga ati agbara imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo jẹ okùnfà pípa awọn ẹṣẹ rẹ.

Igbagbọ maa n ju ara wọn lọ pẹ̀lú bi ohun ti n bẹ ninu ọkan ba ṣe ju ara lọ nibi imọkanga, awọn kan ninu awọn eniyan a maa sọ gbolohun yii ṣùgbọ́n wọn maa fi iya jẹ wọn ni odiwọn awọn ẹṣẹ wọn.

التصنيفات

Nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin., Nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin., Awọn ọla ti n bẹ fun mimu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo, Awọn ọla ti n bẹ fun mimu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo