إعدادات العرض
Iyẹn ni Shaitan kan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ti fura mọ ọn, ki o wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ lẹẹmẹta
Iyẹn ni Shaitan kan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ti fura mọ ọn, ki o wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ lẹẹmẹta
Lati ọdọ Uthman ọmọ Abul 'Aas- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju o wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju Shaitan ti wa laaarin mi ati irun mi ati kika mi, ti o n da a ru mọ mi loju, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Iyẹn ni Shaitan kan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ti fura mọ ọn, ki o wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ lẹẹmẹta", o sọ pe: Mo wa ṣe bẹẹ ni Ọlọhun ba mu u kuro lọdọ mi.
الترجمة
العربية English မြန်မာ Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands اردو Bahasa Indonesia ئۇيغۇرچە বাংলা Türkçe සිංහල हिन्दी Tiếng Việt Hausa Kiswahili ไทย پښتو অসমীয়া دری Кыргызча Lietuvių Kinyarwanda नेपाली తెలుగు Bosanski ಕನ್ನಡ Kurdî മലയാളം Oromoo Română Italiano Soomaali Shqip Српски Українська Wolof Moore Tagalog Malagasy தமிழ் Azərbaycan فارسی ქართული 中文 Magyarالشرح
Uthman ọmọ Abul 'Aas- ki Ọlọhun yọnu si i- wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju Shaitan kọdi laaarin mi ati laaarin irun mi, ti o kọ ipaya fun mi nibẹ, ti o da kika mi ru ti o si ko iyemeji ba mi nibẹ, Ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba sọ fun un pe: Ìyẹn ni Shaitan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ri eyi ti o si fura mọ ọn, dirọ mọ Ọlọhun, ki o si wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, ki o si fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ pẹlu itọ diẹ lẹẹmẹta, Uthman sọ pe: Mo ṣe nnkan ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pa mi láṣẹ pe ki n ṣe, ni Ọlọhun si mu u kuro lọdọ mi.فوائد الحديث
Pataki ipaya ati wiwa ọkan lori irun, ati pe dajudaju Shaitan maa n gbiyanju lati da ìrun rú ati lati jẹ ki èèyàn maa ṣe iyèméjì lórí ìrun.
Ṣíṣe wiwa iṣọra kuro lọdọ Shaitan lofin nibi royiroyi rẹ lori irun, pẹlu títu itọ́ si ẹgbẹ osi lẹẹmẹta.
Alaye nipa nnkan ti awọn sahaabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- wa lori rẹ ninu ṣiṣẹri pada wọn sọ́dọ̀ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi nnkan ti o ba n ṣẹlẹ̀ si wọn ninu awọn ìṣòro titi yoo fi wa ojútùú si i fun wọn.
Wíwà ni ààyè ọkan awọn saabe, ati pe ohun ti o mumu laya wọn ni ọrun.