Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni gbogbo igba

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni gbogbo igba

Lati ọdọ ‘Āisha – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni gbogbo igba.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

‘Āisha iya gbogbo mu’mini – ki Ọlọhun yọnu si i – n sọ pe dajudaju Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti ojukokoro rẹ pọ gidi gan lori riranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ati pe dajudaju o jẹ ẹni ti maa n ranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni gbogbo igba ati aaye ati ìṣesí.

فوائد الحديث

Wọn o ṣe imọra kuro nibi ẹgbin kekere ati nla ni majẹmu fun iranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – maa n dunni mọ́ iranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.

Ṣiṣenilojukokoro lori iranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni ọpọlọpọ ni gbogbo igba lati fi kọṣe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ayaafi ni awọn ìṣesí ti wọn kọ ṣiṣe iranti nibẹ, gẹgẹ bíi asiko gbigbọ bukaata (itọ tabi igbẹ).

التصنيفات

Àwọn ìdájọ́ Kuraani ati Mus'haf