O ti to fun ẹ ki o fi ọwọ rẹ mejeeji ṣe bayii» lẹyin naa ni o fi ọwọ rẹ mejeeji lu ilẹ ni ẹẹkan, lẹyin naa ni o fi osi pa ọtun, ati ẹyin ọwọ rẹ mejeeji ati oju rẹ

O ti to fun ẹ ki o fi ọwọ rẹ mejeeji ṣe bayii» lẹyin naa ni o fi ọwọ rẹ mejeeji lu ilẹ ni ẹẹkan, lẹyin naa ni o fi osi pa ọtun, ati ẹyin ọwọ rẹ mejeeji ati oju rẹ

Lati ọdọ Ammār ọmọ Yāsir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ran mi ni iṣẹ kan, ni mo ba ni janaba ti mi o si ri omi, ni mo ba po ara mọ erupẹ gẹgẹ bi ẹranko ṣe maa n po ara mọ ọn, lẹyin naa ni mo wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ni mo si sọ iyẹn fun un, o si sọ pe: «O ti to fun ẹ ki o fi ọwọ rẹ mejeeji ṣe bayii» lẹyin naa ni o fi ọwọ rẹ mejeeji lu ilẹ ni ẹẹkan, lẹyin naa ni o fi osi pa ọtun, ati ẹyin ọwọ rẹ mejeeji ati oju rẹ».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ran Ammār ọmọ Yāsir - ki Ọlọhun yọnu si i - lọ si irin-ajo kan fun awọn bukaata rẹ kan, ni janaba ba ṣẹlẹ si i latara ibalopọ tabi dida atọ pẹlu adun, ti ko si ri omi ti yíò fi wẹ, O jẹ ẹni ti ko mọ idajọ tayammam (Aluwala eleepẹ) fun janaba, amọ o mọ idajọ rẹ fun ẹgbin kekere, Ni o ba gbiyanju ti o si lero pe gẹgẹ bi o ṣe maa fi iyẹpẹ ti o wa ni ori ilẹ pa awọn orike aluwala kan nibi ẹgbin kekere, nitori naa tayammam fun janaba naa gbọdọ ṣẹlẹ pẹlu fifi iyẹpẹ kari gbogbo ara; lati fi ṣe deede omi, ni o ba yi ara mọ iyẹpẹ titi ti o fi kari ara ti o si lọ kirun, Nigba ti o wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o sọ iyẹn fun un; ki o le mọ boya o wa loju ọna abi bẹẹkọ? Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ṣe alaye fun un bi a ṣe n ṣe imọran kuro nibi ẹgbin mejeeji kekere gẹgẹ bii itọ, ati ńlá gẹgẹ bii janaba: Oun naa ni ki o fi ọwọ rẹ mejeeji lu ilẹ ni ẹẹkan, lẹyin naa ki o pa osi lori ọtun, ki o fi pa ẹyin ọwọ rẹ mejeeji ati oju rẹ.

فوائد الحديث

Jijẹ dandan wiwa omi siwaju tayammam (Aluwala eleepẹ).

Ṣiṣe tayammam (Aluwala eleepẹ) lofin fun ẹni ti o ni janaba ti ko si ri omi.

Tayammam (Aluwala eleepẹ) fun ẹgbin nla da gẹgẹ bii tayammam fun ẹgbin kekere.

التصنيفات

Aluwala elérùpẹ̀