Ẹ bẹru Ọlọhun Oluwa yin, ẹ ki irun wakati marun-un yin, ẹ gba awẹ oṣu yin, ẹ yọ saka awọn dukia yin, ẹ tẹle adari àlámọ̀rí yin ẹ maa wọ alujanna Olúwa yín

Ẹ bẹru Ọlọhun Oluwa yin, ẹ ki irun wakati marun-un yin, ẹ gba awẹ oṣu yin, ẹ yọ saka awọn dukia yin, ẹ tẹle adari àlámọ̀rí yin ẹ maa wọ alujanna Olúwa yín

Lati ọdọ Abu Umaamah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣe khutubah ni hajj idagbere, o sọ pe: "Ẹ bẹru Ọlọhun Oluwa yin, ẹ ki irun wakati marun-un yin, ẹ gba awẹ oṣu yin, ẹ yọ saka awọn dukia yin, ẹ tẹle adari àlámọ̀rí yin ẹ maa wọ alujanna Olúwa yín".

[O ni alaafia] [Ibnu Hibbaan ni o gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe khutubah ni ọjọ 'Arafah, ni hajj idagbere, ni ọdun kẹwàá ninu hijira, wọn sọ ọ ni orúkọ yẹn; nitori pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dagbere fun awọn eniyan nibẹ, O pa awọn eniyan patapata láṣẹ lati bẹru Oluwa wọn pẹlu mimu awọn àṣẹ Rẹ ṣẹ ati jijina si awọn ẹ̀kọ̀ Rẹ. Pe ki wọn maa ki awọn irun maraarun-un ti Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe wọn ni ọran-anyan ni ọsan ati alẹ. Pe ki wọn maa gba awẹ oṣu Ramadan. Pe ki wọn maa yọ saka awọn dukia fun awọn ti wọn lẹtọọ si i ki wọn si ma ṣe ahun pẹlu rẹ. Pe ki wọn maa tẹle awọn ti Ọlọhun fi ṣe adari le wọn lori, yàtọ̀ si ibi ṣiṣẹ Ọlọhun, Ẹni ti o ba ṣe awọn nnkan ti a dárúkọ yìí, ẹsan rẹ ni wiwọ alujanna.

فوائد الحديث

Awọn iṣẹ yii wa ninu awọn okunfa wiwọ alujanna.

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun awọn iṣẹ rere