إعدادات العرض
Emi wà pẹlu aba ti ẹru mi dá sí mi, Emi si wà pẹlu rẹ nigbati o ba rántí Mi
Emi wà pẹlu aba ti ẹru mi dá sí mi, Emi si wà pẹlu rẹ nigbati o ba rántí Mi
Lati ọdọ Abu Hurayrah - kí Ọlọhun yọnu si i - o sọ bayi pe: Òjíṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọ pé: Allah Ọlọhun ti O gbọngbọn ti O ga jùlọ sọ pé: Emi wà pẹlu aba ti ẹru mi dá sí mi, Emi si wà pẹlu rẹ nigbati o ba rántí Mi , ti o ba rántí mi ninu ẹmi rẹ Emi naa yóò rántí rẹ ninu ẹmi Mi, ti o ba rántí mi làárìn awọn ìjọ Emi naa yóò rántí rẹ láárín awọn ti wọn lóore jù ìjọ tiẹ lọ, ti o bá sun mọ mi ni iwọn àlàfo ni na ọmọnika tán Emi yóò sún mọ ni iwọn ni na igunpá, ti o bá sun mọ Mi ni iwọn gigun apá Emi yóò sún mọ ni iwọn gigun ni na apa méjèejì lẹẹkan naa, ti o bá wá bá mi ni eniti nrin, Emi yóò wá bá ní Ẹni ti nyara.
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Bahasa Indonesia Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Français Tiếng Việt සිංහල Hausa Kurdî Kiswahili Português தமிழ் Русский Nederlands অসমীয়া ગુજરાતી پښتو മലയാളം नेपाली ქართული Magyar తెలుగు मराठी Македонски Svenska Moore Română Українська ไทย ਪੰਜਾਬੀ دری አማርኛ Wolof ភាសាខ្មែរ ಕನ್ನಡ Malagasy Српскиالشرح
Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba) fún wa niro pe dájúdájú Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pé: Emi wà pẹlu aba ẹru mi sí mi, Emi yóò sì máa bá a lo nibamu aba rẹ sí mi, pẹlu ini ireti ati ifun ni ni ireti amojukuro, bẹẹni ma máa ṣe oore eyi ti nfọkan sí lọdọ mi, tabi awọn nkan mii; mo wà pẹlu rẹ pẹlu ikẹ ati ifini se kongẹ daada ati itọsọna ati amojuto ati ikun lọwọ nigbati o ba rántí mi. Ti o bá seranti mi ninu ọkan rẹ ni òun nìkan ti ẹnikankan kò si ni bẹ pẹlu sise afọmọ ati gbólóhùn pe kò sí Ọlọhun míràn to yẹ kaa maa sìn àyàafi Allah, tabi awọn ìrántí mii, maa rántí rẹ ninu ẹmi Mi. Ti o bá rántí Mi láàrin àwọn akojọ kan, Emi naa yóò rántí rẹ láárín awọn akojọ ti wọn pọ ti wọn si dáa jù wọn lọ. Ẹni tí o ba sun mọ Ọlọhun ni iwọn ina ika ọwọ mararun tan Ọlọrun yóò se alekun fun yóò wá sun mọ ni iwọn igunpa kan. Ti o bá sun mọ ni iwọn igunpa kan Ọlọhun yóò sún mọ ni iwọn ina apá mejeeji tan lẹ kan naa. Ti o ba wa bá Ọlọhun ni ẹnití nrin Ọlọhun yóò wá ba ni yara yara. Ti ẹru (eniyan) bá sun mọ Oluwa rẹ pẹlu imáa tẹle àṣẹ Rẹ ti o kọ ju sí daada, dajudaju Ọlọhun Oluwa ti O ga jù lọ yóò se alekun ni isunmọ rẹ pada yóò máa jẹ ẹsan iru nkan to se. Gbogbo igba ti ijẹ ẹru fún Ọlọhun ti olugbagbọ ba ti pé fún Oluwa rẹ náà ni Ọlohun ti Ọ̀la Rẹ ga yóò sún mọ, ọrẹ Ọlohun ati ẹsan Rẹ pọ jù iṣẹ ati wahala ti ẹru se lori rẹ lọ, eyi ti o ṣẹlẹ nipe ẹsan Ọ̀lọhun tẹwọn lori iṣẹ ẹru pẹlu ọna ati iye iṣẹ tó ṣe. Olugbagbọ ododo yóò máa daba daada sí Oluwa rẹ, yóò sì máa ṣiṣẹ daada, yóò sì máa yàrá sise daada, yóò sì máa ṣe alekun iṣẹ tí yóò fi pàdé Ọlọhun.فوائد الحديث
Hadith yìí wa nínú hadith ti Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati Ọlà Rẹ máa ba a) gbawa lati ọdọ Oluwa rẹ, Òun ni wọn npe ni Ọrọ to mọ tàbí Ọrọ Ọlọhun, ohun ni hadith to se pe gbólóhùn ati ìtumọ rẹ wá lati ọdọ Ọlọhun, Sugbọn koni awọn nkan idaṣa lẹṣa Al-Qur'an lára, èyí ti o fí yatọ sí ọrọ mii, bi kika Al-Qur'an fún ìjọsìn ati iṣe imọra síwaju ki a to le kàá, ati ifi peni nija ati iko agara bá àwọn eniyan lati mu iru rẹ wá, ati awọn nkan mii yatọ sí eleyi.
Al-Aajurriy sọ pe: dajudaju awọn ẹni òdodo wọn a ṣe iroyin Ọlọhun ti O gbángban ti O si tobi ju pẹlu awọn iroyin ti O fi royin ara Rẹ Ọba to gbángban ti o Tobi, ati pẹlu bi Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) se royin Rẹ, ati bi awọn saabé (awọn musulumi akọkọ) ki Ọlọhun yọnu si wọn se royin rẹ, eleyi ni ilana awọn oni mimọ ti wọn tẹlé àlàalẹ Anọbi ti wọn ko da adadaalẹ. O ti pari. Awọn ti wọn tẹlé Sunna (ilana Anọbi) wọn a ṣe afirinlẹ awọn orukọ ati iroyin bi Ọlọhun se fi rinlẹ fún ara Rẹ, lai yi ìtumọ sí bò mí, láì túmọ rẹ bi ko se yẹ, lai fún ìtumọ pe bo se ri ni yii, láì ṣe àfijọ rẹ pẹlu nkan miran, Wọn a sì máa le jina sí Ọlọhun iru nkan ti O bá le jina sí ara Rẹ, wọn a si gbe ẹnu dakẹ ni bi nkan ti Ọlọhun o fi kan rinlẹ tabi le jina. Ọlọhun ti O ga jù lọ sọ pé: (Kosi nkankan ti o dàbí Ọlọhun tabi ti o jọ Oun ni Olùgbọ ati Olurina).
Iṣẹ ni lati wa papọ mo idaba daada pẹlu Ọlohun, Al-Hasanul-Basiriy sọ pé: dájúdájú olugbagbọ òdodo ni a máà daba daada pẹlu Oluwa rẹ, yóò sì ṣe iṣẹ ni daada, dajudaju poki eniyan (ẹni tí o yápa sí àṣẹ Ọlọhun) a maa da àbá aburú sí Oluwa Rẹ yoo si se iṣẹ ni aburu.
Al-Qurtubiy sọ pé: wọn sọ pé: ìtumọ "ẹrù Mi dá àbá simi" aba pe máa dá loun nigbati o ba ke pè Mí, ati àbá gbigba iwa aforijin rẹ nigbati o ba tiwa (ṣíwọ kuro ni bi ẹṣẹ), ati àbá riri aforijin nigbati o ba tọrọ idarijin, ati àbá ifọwọsi nigbati o ba se ìjọsìn pẹlu awọn majẹmu rẹ ni ẹniti o ṣe amudani adehun òtítọ Ọlọhun, nitoribẹ ni o fi yẹ fún ọmọ eniyan ki o gbiyanju lati máa ṣe nkan ti o yẹ kose ni eni ti yóò mọ dájú pé Ọlọhun yóò gba yóò sì ṣe aforijin fún oun; nitoripe O ti ṣe adehun bẹ, bẹ si ni Ọlọhun kìí yẹ adehun Rẹ, ti o ba di adisọkan tabi o daba pe Ọlọhun ko níí gba, tabi ko le ṣe oun lanfaani eleyi ni isọ ireti nu ninu ikẹ Ọlọhun, ki a si sọ iretinu nibi ikẹ Ọlọhun o wa ninu awọn ẹsẹ nla nla, ẹni tó bá ku lori bayi wọn yoo pati sára àbá ati ero rẹ gẹgẹ bí o se wá ninu awọn apakan ọna hadith ti a sọ, "ki ẹru Mi daba nkan ti o bá wù nipa Mi", o sọ pe: ṣugbọn idaba aforinjin pẹlu itẹpẹlẹ mọ ẹsẹ aimọkan ni eleyi jẹ ati igbatanjẹ.
Iseni lójú kòkòrò lati se ọpọlọpọ ìrántí Ọlọhun ninu ọkan rẹ ati pẹlu ahán rẹ lapapọ, ninu ẹmi ati ọkan rẹ ni yóò ti ni ifoya fún Ọlohun ti yóò sì máa rántí titobi rẹ ati ẹtọ rẹ yóò sì máa nireti si ọdọ Rẹ, yóò sì máa gbé tobi yóò nifẹ rẹ pẹlu idaba daada si yóò sì máa ṣiṣẹ ni mimọ fún Un, yóò ma wí pẹlu ahán: Mimọ ni fún Ọlọhun, gbogbo iyin ati ọpẹ ti Ọlọhun níí ṣe, Kosi nkan mi to lẹ tọsí ìjọsìn ayaafi Allah (Ọlọhun), Ọlọhun lo tobi jùlọ, kosi ọgbọn kan tabi agbára kan àyàafi pẹlu aṣẹ Ọlọhun.
Ọmọ baba Jamrah sọ pé: ẹni tí o ba rántí Ọlọhun ni ẹnití nfoya (ti nbẹru) Ọlọhun yóò fi lọkan balẹ .
Gbólóhùn Ashibr ni: Aaye àlàfo ti o wa laarin ika ọmọ Landirin titi dé ika àtànpàkò nigbati a ba na ọwọ, Adhiraa'u ni: alafo aaye ti o wa laarin eteeti ika aarin titi dé eegun igunpa, Al-Baa'u ni: inantan gigun apá mejeeji eniyan looro ati ibu fifẹ igbaaya, ohun lo jẹ odiwọn gigun apá mẹrin.