إعدادات العرض
Fiforikanlẹ fun Ọlọhun lọpọlọpọ jẹ dandan fun ẹ, dajudaju o ko nii forikanlẹ fun Ọlọhun ni iforikanlẹ ẹẹkan, afi ki Ọlọhun fi gbé ẹ ga nipo, ki O si fi ba ẹ pa ẹṣẹ rẹ
Fiforikanlẹ fun Ọlọhun lọpọlọpọ jẹ dandan fun ẹ, dajudaju o ko nii forikanlẹ fun Ọlọhun ni iforikanlẹ ẹẹkan, afi ki Ọlọhun fi gbé ẹ ga nipo, ki O si fi ba ẹ pa ẹṣẹ rẹ
Lati ọdọ Ma'daan ọmọ Abu Tolha Al-Ya'mariy o sọ pe: Mo pade Thaobaan ẹru ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- mo wa sọ pe: Fun mi ni iro nipa iṣẹ kan ti mo ba n ṣe e Ọlọhun maa fi mu mi wọnu alujanna? Tabi o sọ pe mo sọ pé: pẹlu eyi ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ ninu awọn iṣẹ, o ba dakẹ. Lẹ́yìn naa mo bi i leere ni o ba dakẹ. Lẹ́yìn naa mo bi i leere ni ẹẹketa, o wa sọ pe: Mo beere nipa ìyẹn lọwọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Fiforikanlẹ fun Ọlọhun lọpọlọpọ jẹ dandan fun ẹ, dajudaju o ko nii forikanlẹ fun Ọlọhun ni iforikanlẹ ẹẹkan, afi ki Ọlọhun fi gbé ẹ ga nipo, ki O si fi ba ẹ pa ẹṣẹ rẹ" Ma'daan sọ pe: Lẹyin naa mo pade Abu Dardaa mo si bi i leere, o si sọ fun mi: Iru nnkan ti Thaobaan sọ fun mi.
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Tiếng Việt සිංහල Hausa Kurdî Kiswahili Português தமிழ் دری অসমীয়া አማርኛ Svenska ไทย Кыргызча ગુજરાતી नेपाली Română മലയാളം Nederlands Oromoo తెలుగు پښتو Soomaali Kinyarwanda Malagasyالشرح
Wọn beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa iṣẹ ti o maa jẹ okunfa fun wiwọnu alujanna tabi nipa eyi ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun olubeere pe: Dunni mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ iforikanlẹ nibi irun, o ko nii forikanlẹ fun Ọlọhun ni iforikanlẹ kan afi ki O fi gbe ẹ ga nípò, ki O si fi i ṣe aforijin fun ẹ.فوائد الحديث
Ṣíṣe Musulumi lojukokoro lori àbójútó irun, ọran-anyan ni ati akigbọrẹ; nitori pe o ko iforikanlẹ sinu.
Alaye agbọye ẹsin awọn saabe ati imọ wọn pe dajudaju alujanna wọn ko lee wọ ọ- lẹyin ikẹ Ọlọhun- afi pẹlu iṣẹ.
Iforikanlẹ nibi irun wa ninu eyi ti o tobi julọ ninu awọn okunfa igbe awọn ipo ga, ati aforijin àwọn ẹṣẹ.
التصنيفات
Ọla ti o n bẹ fun irun