ẹru kan ko ni se ibasiri fún ẹrú kan láyé nbi ayaafi ki Ọlọhun se ibasiri fún un ni ọjọ igbende

ẹru kan ko ni se ibasiri fún ẹrú kan láyé nbi ayaafi ki Ọlọhun se ibasiri fún un ni ọjọ igbende

Lati ọdọ Abu Hurayrah - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: "ẹru kan ko ni se ibasiri fún ẹrú kan láyé nbi ayaafi ki Ọlọhun se ibasiri fún un ni ọjọ igbende".

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) n salaye fun wa pé musulumi kan ko ni bo asiri ọmọ Iya rẹ tó jẹ musulumi nipa àlámọ̀rí kan ninu awọn àlámọ̀rí, ayaafi ki Ọlọhun bo asiri rẹ ni ọjọ igbende, iran iṣẹ ti a ba se náà ni a o gba ẹsan rẹ, yóò wa jasipe bibo àṣírí Ọlọhun fún un ni pé yóò bo asiri awọn laifi rẹ àti àwọn ẹsẹ rẹ lati máa ṣe itanka rẹ lọdọ awọn ti wọn wani ibi gbangba Al-kiyaoma, o si le je pe bibo asiri rẹ ni ki Ọlọhun má ṣe iṣiro rẹ tabi ki o má ti ẹ mẹnu kaan rárá.

فوائد الحديث

Wiwa ni ibamu sí ilana ẹṣin pe ki a se bibo àṣírí fún musulumi nigbati o bá wu iwa ẹsẹ kan, pẹlu ki a tako iwa naa, ki a sì máa fún un ni ìkìlọ̀ ati imọran, ki a sì máa fi Ọlọhun fún un ni ifoya, sugbọn tí o bá wà nínú àwọn alaburu ati àìda ti wọn nse ẹsẹ ati iwa poki ni gbangba, kò tọ láti bo asiri wọn, nitori ki a bo asiri wọn yóò jẹ ki wọn maa ni ìgboyà láti máa dá ẹsẹ, a ni lati gbe ọrọ wọn lọ sí ọdọ awọn apàṣẹ, koda ki o jasipe a darukọ rẹ, nitoripe oun náà ti se afihan ìyapa ati ìwà poki rẹ ati ẹsẹ rẹ.

Iseni lójúkòkòrò láti máa bo asiri ẹlòmíràn.

Ninu ìwúlò biboni lasiri : Fifun ẹlẹsẹ ní ànfàaní igbalaaye láti yẹ ara rẹ wò kí o si ronú piwada sí ọdọ Ọlọhun; nitoripe ṣiṣe ikede laifi ati ibi ti enikan kùsí wa lara itan ibajẹ ka, aa si maa ba ojú ọjọ àwùjọ jẹ, bẹẹ ni aa maa se awọn eniyan loju kòkòrò lati máa ṣe iru rẹ.

التصنيفات

Taohiid ti àwọn orúkọ ati awọn iroyin, Awọn iwa ẹyin