Isilaamu ni ki o jẹ́rìí pe ko si ẹni tí ìjọsìn tọ si lododo ayafi Ọlọhun, ati pe Muhammad ni ojiṣẹ Rẹ, ki o maa gbe ìrun dúró, ki o maa yọ sàká, ki o maa gba aawẹ Ramadan, ki o maa ṣe hajj ti o ba ni ikapa ọ̀nà lọ si ibẹ

Isilaamu ni ki o jẹ́rìí pe ko si ẹni tí ìjọsìn tọ si lododo ayafi Ọlọhun, ati pe Muhammad ni ojiṣẹ Rẹ, ki o maa gbe ìrun dúró, ki o maa yọ sàká, ki o maa gba aawẹ Ramadan, ki o maa ṣe hajj ti o ba ni ikapa ọ̀nà lọ si ibẹ

Láti ọ̀dọ̀ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Láàrin ìgbà tí a wa ni ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ kan, ni arákùnrin kan ba yọ si wa, ti aṣọ rẹ funfun gan, ti irun rẹ naa si dúdú gan, a ko ri oripa ìrìn-àjò ni ara rẹ, ẹni kankan ko si mọ ọn ninu wa, titi ti o fi jókòó si ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o si fi eékún rẹ méjèèjì tì sí ara eékún rẹ méjèèjì, o wa gbe ọwọ́ rẹ méjèèjì lori itan rẹ, o wa sọ pé: Irẹ Muhammad, sọ fún mi nipa Islam, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Isilaamu ni ki o jẹ́rìí pe ko si ẹni tí ìjọsìn tọ si lododo ayafi Ọlọhun, ati pe Muhammad ni ojiṣẹ Rẹ, ki o maa gbe ìrun dúró, ki o maa yọ sàká, ki o maa gba aawẹ Ramadan, ki o maa ṣe hajj ti o ba ni ikapa ọ̀nà lọ si ibẹ”, o sọ pé: Òdodo ni o sọ, o sọ pé: Ẹnu yà wá fun un, o n bi i leere, o si tun n sọ pé òdodo ni o sọ, o sọ pé: Sọ fun mi nipa igbagbọ, o sọ pé: “Ki o ni igbagbọ ninu Ọlọhun, ati awọn malaika Rẹ̀, ati awọn ìwé Rẹ, ati awọn ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ́ ìkẹyìn, ki o si ni igbagbọ ninu kádàrá, oore rẹ ni ati aburu rẹ”, o sọ pe: Òdodo ni o sọ, o sọ pe: Sọ fun mi nipa ṣíṣe dáadáa, o sọ pe: “Ki o maa jọ́sìn fun Ọlọhun bii pe o n ri I, ti ìwọ ko ba ri I, Òun n ri ọ”, o sọ pe: Sọ fún mi nipa àsìkò ti aye maa parẹ, o sọ pe: “Ẹni ti wọn n beere nipa nǹkan lọ́wọ́ rẹ ko ni imọ nipa nǹkan naa ju ẹni tí n beere lọ”, o sọ pe: Sọ fún mi nipa awọn àmì rẹ, o sọ pe: “Ki ẹrú lóbìnrin bi olówó rẹ, ati ki o ri awọn ti ko wọ bàtà ti wọn wa ni ihoho ti wọn jẹ tálákà tí wọn n da ẹran jẹ, ti wọn yoo maa fi ile gíga ṣe iyanran”, o sọ pe: Lẹ́yìn naa o pẹyin da, mo wa wa nibẹ fun ìgbà pípẹ́, lẹ́yìn náà ni o wa sọ fún mi pe: “Irẹ Umar, ǹjẹ́ o mọ onibeere naa?”, mo sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “Jibril ni, o wa ba yin lati kọ yin ni ẹsin yin”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pe Jibril wa ba àwọn saabe ni àwòrán arákùnrin kan ti wọn kò mọ̀. Lára àwọn ìròyìn rẹ ni pe àwọn aṣọ rẹ funfun gan, ti irun rẹ naa si dudu gan, wọn ko ri oripa ìrìn-àjò lára rẹ bii híhàn wàhálà, ati eruku, ati ki irun ri wúruwùru, ati ki aṣọ dọ̀tí, ẹni kankan ko si mọ ọn ninu awọn ti wọn wa ni ìkàlẹ̀, ti wọn si jókòó ni ọdọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a), ni o wa jókòó ni iwájú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ìjókòó akẹ́kọ̀ọ́, o wa bi i leere nipa Isilaamu, o wa da a lóhùn pẹ̀lú àwọn origun ti o ko fifi ijẹrii mejeeji rinlẹ sínú, ati mimojuto irun wákàtí márùn-ún, ati yíyọ sàká fun awọn ti wọn ni ẹtọ si i, ati gbigba aawẹ oṣù Ramadan, ati pípé ọranyan hajj fun ẹni tí ó bá ni ikapa. Onibeere wa sọ pé: Òdodo ni o sọ, àwọn saabe wa ṣe eemọ latara ìbéèrè rẹ ti n tọka si àìní imọ rẹ ti o hàn si wọn, lẹ́yìn náà ni o tun wa n sọ pe òdodo ni o sọ. Lẹ́yìn naa ni o bi i leere nipa igbagbọ, o wa da a lóhùn pẹ̀lú àwọn origun mẹ́fà yii ti o ko igbagbọ ninu bibẹ Ọlọhun ati awọn ìròyìn Rẹ sinu, ati ṣíṣe E ni Ọ̀kan pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ Rẹ bii dídá ẹ̀dá, ati ṣíṣe E ni Ọkan pẹlu ìjọsìn, ati pe àwọn malaika ti Ọlọhun da latara imọlẹ ẹrú alapọn-ọnle ni wọn, wọn kii yapa àṣẹ Ọlọhun, ati ìgbàgbọ́ nínú àwọn tira ti a sọ̀kalẹ̀ fun awọn ojiṣẹ lati ọdọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, gẹgẹ bii Kuraani, ati Taoreeta, ati Injiila, ati eyi ti o yatọ si wọn, ati ìgbàgbọ́ nínú àwọn ojiṣẹ ti wọn n ba Ọlọhun mu ẹsin Rẹ de ọdọ àwọn èèyàn, ninu wọn ni Nuuh, ati Ibrahim, ati Musa, ati Isa, ìgbẹ̀yìn wọn ni Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a), ati awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn Anọbi ati awọn Ojiṣẹ, ati ìgbàgbọ́ ninu ọjọ́ ìkẹyìn, ohun ti n bẹ lẹyin ikú ti ko sínú rẹ̀ bii sàréè ati iṣẹmi lẹ́yìn ikú, ati pe wọn maa gbe ọmọniyan dìde lẹ́yìn iku, o si tun maa ṣe ìṣirò, nínú ki ìkángun rẹ jẹ alujanna tabi iná, ati ìgbàgbọ́ pe Ọlọhun ti kádàrá gbogbo nǹkan ni ibamu si ohun ti O ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, ti o si ba ọgbọ́n Rẹ̀ mu ati àkọsílẹ̀ Rẹ, ati fifẹ Rẹ fun un, ati ṣiṣẹlẹ rẹ ni ibamu si ohun ti O kádàrá, ti O si dá a fun un. Lẹyin naa ni o bi i leere nipa ṣíṣe dáadáa, o wa sọ fún un pé ṣíṣe dáadáa naa ni ki o maa jọ́sìn fun Ọlọhun bii pe o n ri I, ti ko ba wa le de ipò yii, Ki o yaa maa jọ́sìn fun Ọlọhun bii pe Ọlọhun n ri i, akọkọ ni ipò rírí, oun ni o si ga jù, ìkejì ni ipò ìpayà Lẹ́yìn naa o bi i leere pe igba wo ni ayé maa parẹ? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣàlàyé pe Ọlọhun nikan ni O mọ ìgbà tí ayé maa parẹ, ẹda kankan ko mọ̀ ọ́n, ati ẹni ti wọn n beere nipa rẹ lọ́wọ́ rẹ ni ati ẹni tí n beere. Lẹyin naa ni o bi i leere nipa awọn àmì ti ayé ba fẹ parẹ? O wa ṣàlàyé pe nínú àwọn àmì rẹ ni ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ẹrú lóbìnrin ati awọn ọmọ wọn, tabi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣiṣẹ ìyá lati ọwọ àwọn ọmọ wọn ti wọn maa ba wọn lo bii ẹrú, wọn maa tẹ́ ayé silẹ fun àwọn adaranjẹ ati awọn tálákà ni ìgbà ìkẹyìn, wọn maa ba ara wọn ṣe iyanran nibi ṣíṣe ilé ni ọ̀ṣọ́ ati kíkọ́ ọ. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé onibeere naa ni Jibril, o wa lati wa kọ́ àwọn saabe ni ẹsin ti o dúró tọ́ yii.

فوائد الحديث

Dídára iwa Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati pe o maa n jókòó pẹ̀lú àwọn saabe rẹ, àwọn naa si maa n jókòó ti i.

Ibofinmu ṣíṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú onibeere ati sisun un mọ́ra ki o le rọ̀ ọ́ lọrun lati beere láìní kákò tàbí bẹ̀rù.

Ẹ̀kọ́ pẹ̀lú olùkọ́ gẹgẹ bi Jibril- ki ọla maa ba a- ṣe ṣe, nibi ti o ti jókòó ni iwájú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ìjókòó ẹni tí ó ní ẹ̀kọ́ láti gba imọ lọ́dọ̀ rẹ.

Awọn origun Isilaamu márùn-ún ni, awọn ìpìlẹ̀ igbagbọ mẹ́fà ni.

Ti Isilaamu ati ìgbàgbọ́ ba para pọ̀, wọn maa túmọ̀ Isilaamu si awọn alamọri ti ó hàn, wọn si maa túmọ̀ igbagbọ si awọn alamọri ti o pamọ.

Àlàyé pe ẹsin ni ipò ti o yàtọ̀ síra, ipò akọkọ: Isilaamu, ìkejì: Igbagbọ, ìkẹta: Ṣíṣe dáadáa, oun si ni o ga jù.

Ìpìlẹ̀ ni pe onibeere ko ni imọ, aimọkan ni o maa mu u bèèrè; torí ẹ ni ẹnu ṣe ya àwọn saabe latara ìbéèrè rẹ ati sisọ pe òdodo ni o sọ.

Bibẹrẹ nǹkan pẹ̀lú bi o ba ṣe pàtàkì jù sí; torí pé wọn bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ijẹrii mejeeji nibi itumọ Isilaamu, wọn si bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú igbagbọ ninu Ọlọhun nibi itumọ igbagbọ.

Ki onibeere beere ohun ti ó ni imọ nipa rẹ lọ́wọ́ onimimọ ki ẹlòmíì lè mọ̀.

Ọlọhun nikan ni O mọ ìgbà tí ayé maa parẹ́.

التصنيفات

Adisọkan