“Dájúdájú èèyàn ti Ọlọhun koriira jù ni alátakò ti o le julọ”

“Dájúdájú èèyàn ti Ọlọhun koriira jù ni alátakò ti o le julọ”

Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: “Dájúdájú èèyàn ti Ọlọhun koriira jù ni alátakò ti o le julọ”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga n koriira ninu awọn èèyàn ẹni ti o le ni àtakò ti o si maa n sáábà ṣe àtakò, ẹni tí kii tẹrí ba fun òdodo, ti o maa n gbìyànjú láti da a pada pẹlu iyàn jíjà rẹ, tabi ki o maa ṣe àtakò lori ododo, ṣùgbọ́n o maa ki aṣeju bọ̀ ọ́, o tun maa ṣe àtakò láìní imọ.

فوائد الحديث

Ki ẹni tí a ṣe àbòsí si beere ẹtọ rẹ nípasẹ̀ gbigbe ẹjọ́ lọ ba adajọ ti o ba òfin mu, eleyii kò kó sinu àtakò ti ko dára.

Ìjiyàn ati àtakò wa ninu awọn ìpalára ahọn ti o maa n ṣe okùnfà ìpín yẹ́lẹyẹ̀lẹ ati ìkọ̀yìn-sí-ara-ẹni láàrin àwọn Musulumi.

Àtakò ti o dara ni eyi ti o ba jẹ nibi òdodo, ti ọ̀nà ti a gbe e gba naa si dára, o si maa jẹ eyi ti ko dára ti o ba wa fun dida òdodo padà, ati fifi irọ́ rinlẹ, tabi ki o ma si ẹ̀rí kankan fun un.

التصنيفات

Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ, Awọn iwa eebu