إعدادات العرض
“Tí ọmọniyan ba nawo lori awọn ara ile rẹ ti o n reti ẹsan rẹ lọdọ Ọlọhun, saara ni o jẹ fun un”
“Tí ọmọniyan ba nawo lori awọn ara ile rẹ ti o n reti ẹsan rẹ lọdọ Ọlọhun, saara ni o jẹ fun un”
Lati ọdọ Abu Mas’ud- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Tí ọmọniyan ba nawo lori awọn ara ile rẹ ti o n reti ẹsan rẹ lọdọ Ọlọhun, saara ni o jẹ fun un”.
[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Tiếng Việt ئۇيغۇرچە Kurdî Hausa Português മലയാളം తెలుగు မြန်မာ ไทย Deutsch 日本語 پښتو অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands සිංහල Kiswahili தமிழ் دری Magyar Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių Malagasy Română Kinyarwanda नेपाली Српски Wolof Soomaali Moore Українська Български Azərbaycan ქართული тоҷикӣ bm Македонскиالشرح
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ti ọmọniyan ba nawo lori awọn ara ile rẹ ti inawo wọn jẹ dandan fun un, gẹgẹ bii iyawo rẹ ati awọn obi rẹ mejeeji ati ọmọ rẹ ati awọn ti wọn yatọ si wọn, ti o n fi ìyẹn sunmọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti o n reti ẹsan nnkan ti o n na lọdọ Rẹ, dajudaju ẹsan saara n bẹ fun un.فوائد الحديث
Gbígba ẹsan ati laada pẹlu ninawo lori awọn ara ile.
Mu’mini maa n wa ojú rere Ọlọhun ati ẹ̀san ti n bẹ lọdọ Rẹ nibi iṣẹ rẹ.
O lẹtọọ lati ni aniyan daadaa nibi gbogbo iṣẹ, ninu ìyẹn ni iṣesi ninawo lori awọn ara ile.
التصنيفات
Awọn inawo