Njẹ ẹ mọ nnkan ti Oluwa yin sọ?” Wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “O n bẹ ninu awọn ẹru Mi ẹni ti o ji ni onigbagbọ ati ẹni tí o ji ni alaigbagbọ

Njẹ ẹ mọ nnkan ti Oluwa yin sọ?” Wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “O n bẹ ninu awọn ẹru Mi ẹni ti o ji ni onigbagbọ ati ẹni tí o ji ni alaigbagbọ

Lati ọdọ Zaid bn Khalid Al-Juhaniy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki irun asunbaa fun wa ni Hudaibiyah lẹ́yìn ojo ti o rọ̀ ni òru, lẹ́yìn tí ó kírun tán, o kọju si awọn eniyan, o sọ pe: “Njẹ ẹ mọ nnkan ti Oluwa yin sọ?” Wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “O n bẹ ninu awọn ẹru Mi ẹni ti o ji ni onigbagbọ ati ẹni tí o ji ni alaigbagbọ, ẹni tí ó bá sọ pé: Wọ́n rọ òjò fun wa pẹlu ọla Ọlọhun ati aanu Rẹ, ìyẹn ni ẹni tí ó gbagbọ ninu Mi ti o si ṣe aigbagbọ si ìràwọ̀, ṣugbọn ẹni tí o ba sọ pe: Pẹ̀lú ìràwọ̀ bayii bayii, ìyẹn ni ẹni tí o ṣe aigbagbọ ninu Mi, ti o wa ni igbagbọ ninu ìràwọ̀”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki irun asunbaa ni Hudaibiya- oun ni oko kan ti o sunmọ Mẹka- lẹyin ti ojo rọ ni alẹ yẹn, Igba ti o salamọ ti o ki irun rẹ tan o doju kọ awọn eniyan, o si bi wọn pe: Njẹ ẹ mọ nnkan ti Oluwa yin- Alagbara ti O gbọnngbọn- sọ? Wọn da a lohun pe: Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, O sọ pe: Dajudaju Ọlọhun ṣàlàyé pe awọn eniyan pin si meji nigba ti ojo ba rọ: Ipin kan ti o ni igbagbọ ninu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ati ipin ti o jẹ alaigbagbọ ninu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, Ṣugbọn ẹni ti o sọ pe: Wọn rọ ojo fun wa pẹlu ọla Ọlọhun ati ikẹ Rẹ, ti o fi rirọ ojo ti sọ́dọ̀ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-; ìyẹn ni olugbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Aṣẹ̀dá Aṣeyiowuu ninu aye, o si jẹ alaigbagbọ si irawọ. Ṣugbọn ẹni ti o ba sọ pe: Wọn rọ ojo fun wa pẹlu irawọ bayii bayii; ìyẹn ni alaigbagbọ ninu Ọlọhun, olugbagbọ ninu irawọ, o si jẹ aigbagbọ kekere nigba ti o ṣe afiti rirọ ojo si ara irawọ; ati pe Ọlọhun ko ṣe e ni okunfa ti sharia tabi ti kadara, Ṣugbọn ẹni ti o ba ṣe afiti rirọ ojo ati nnkan ti o yàtọ̀ si i ninu awọn ìṣẹ̀lẹ̀ ori ilẹ̀ si ara lilọ-bibọ àwọn ìràwọ̀ nibi yíyọ wọn ati jijabọ wọn, ti o n ni adisọkan pe oun ni ẹni ti o n ṣe e gangan, o ti jẹ alaigbagbọ ni aigbagbọ ti o tobi.

فوائد الحديث

Fifẹ sisọ gbolohun lẹyin rírọ ojo pé: Wọn rọ ojo fun wa pẹlu ọla Ọlọhun ati ikẹ Rẹ.

Ẹni ti o ba ṣe afiti rírọ ojo ati nnkan ti o yàtọ̀ si i si ara irawọ ni ti dida ati mimu-nnkan-bẹ, o ti di alaigbagbọ ni ti aigbagbọ ti o tobi, ṣugbọn ti o ba ṣe afiti rẹ lori pe okunfa ni, o ti di alaigbagbọ ni ti aigbagbọ kekere; nitori pe ko ki n ṣe okunfa ti sharia tabi ti imọlara.

Dajudaju idẹra maa n jẹ okunfa fun aigbagbọ ti wọn ṣe aimore si i, o si maa n jẹ okunfa igbagbọ ti wọn ba dupẹ rẹ.

Kíkọ sisọ gbolohun: “Wọn rọ ojo fun wa pẹlu irawọ bayii bayii, ko da ki wọn gbero asiko pẹ̀lú rẹ, láti dènà àtẹ̀gùn lọ síbi ẹbọ.

Jijẹ dandan siso ọkan papọ mọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nibi fifa awọn idẹra wá, ati titi awọn iya kuro.

التصنيفات

Taohiid ti rubuubiyyah, Awọn nnkan ti wọn maa n ba Isilaamu jẹ, Awọn ipin igbagbọ, Aigbagbọ