“Dajudaju adehun ti o wa laaarin wa ati laaarin wọn ni irun, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ”

“Dajudaju adehun ti o wa laaarin wa ati laaarin wọn ni irun, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ”

Lati ọdọ Buraida- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju adehun ti o wa laaarin wa ati laaarin wọn ni irun, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ”.

[O ni alaafia] [Tirmiziy ni o gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju adehun ati majẹmu ti o wa laaarin awọn Musulumi ati laaarin awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn alaigbagbọ ati awọn ṣọbẹ-selu ni irun kiki, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ.

فوائد الحديث

Titobi ipo irun, ati pe oun ni ipinya ti o wa laaarin olugbagbọ ati alaigbagbọ.

Fifi awọn idajọ Isilaamu rinlẹ pẹlu nnkan ti o ba han ninu isẹsi awọn eniyan yatọ si eyi ti o pamọ.

التصنيفات

Awọn nnkan ti wọn maa n ba Isilaamu jẹ, Aigbagbọ, Ijẹ dandan irun ati idajọ ẹni ti o ba gbe e ju silẹ