Egbe ki o maa ba gbogbo gigisẹ (ti omi o de) ninu ina, ẹ ṣe aluwala yin daadaa

Egbe ki o maa ba gbogbo gigisẹ (ti omi o de) ninu ina, ẹ ṣe aluwala yin daadaa

Lati ọdọ Abdullah ọmọ Amru ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji o sọ pe: A ṣẹri pada pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - lati Makkah lọ si Madina titi ti a fi kan omi ni oju-ọna, awọn ikọ kan yara fun irun Asri, ti wọn si ṣe aluwala ni ẹni ti n kanju, ni a ba wa ba wọn ti awọn gigisẹ wọn han ti omi o si de ibẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: «Egbe ki o maa ba gbogbo gigisẹ (ti omi o de) ninu ina, ẹ ṣe aluwala yin daadaa».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ṣe irin-ajo lati Makkah lọ si Madina ti awọn saabe rẹ si wa pẹlu rẹ, ni oju-ọna wọn wọ́n rí omi, ti apakan ninu awọn saabe sì yara ṣe aluwala fún irun Asri debi pe gbigbẹ awọn gigisẹ fun omi han si kedere, ni Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- wa sọ pe: Iya ati iparun ninu ina n bẹ fun gbogbo olùṣe aseeto nibi fifọ gigisẹ nibi aluwala, o si tun pa wọn lasẹ ki wọn maa ṣe aluwala ni pipe.

فوائد الحديث

Jijẹ dandan fifọ ẹsẹ mejeeji nibi aluwala; torí pé dajudaju ti pipa a ba lẹtọọ ni ko nii ṣe adehun ina fun ẹni ti o fi fifọ gigisẹ silẹ.

Jijẹ dandan fifi omi kari gbogbo awọn oríkèé ara ti a maa n fọ, ati pe ẹnikẹni ti o ba fi aaye kekere kan silẹ ninu nkan ti fifọ rẹ jẹ dandan ni ti imọọmọ ṣe ati ailakasi, irun rẹ ko ni alaafia.

Pataki kikọ alaimọkan ni ẹkọ ati ṣiṣe amọna rẹ.

Onimimọ a maa kọ nkan ti o ba ri nibi rira ọranyan ati sunnah lare pẹlu ọna ti o ba wa ni ibamu.

Muhammad Ishāq Ad-dahlawiy sọ pe: Iran mẹta ni Isbāg: *Ọranyan* oun naa ni mimu omi kari gbogbo aaye naa (oríkèé ara ti a fẹ fọ) ni ẹẹkan, ati *Sunnah* oun naa ni fifọ ni ẹẹmẹta, ati *Eyiti a fẹ* oun naa ni fifa a gun pẹ̀lú fifọ ni ẹẹmẹta.

التصنيفات

Iroyin aluwala