إعدادات العرض
Ti ọkùnrin ba wọ inu ile rẹ, ti o wa ranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ ati nibi oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ pé: Ko si ibusun fun yin ko si si oúnjẹ alẹ naa
Ti ọkùnrin ba wọ inu ile rẹ, ti o wa ranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ ati nibi oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ pé: Ko si ibusun fun yin ko si si oúnjẹ alẹ naa
Lati ọdọ Jabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- pe o gbọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pé: "Ti ọkùnrin ba wọ inu ile rẹ, ti o wa ranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ ati nibi oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ pé: Ko si ibusun fun yin ko si si oúnjẹ alẹ naa, ti o ba wa wọle, ti ko ṣe iranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ, Shaitan maa sọ pé: Ẹ ti ri ibùsùn, ti ko ba ti dárúkọ Ọlọhun nibi oúnjẹ rẹ, o maa sọ pe: Ẹ ti ri ibusun ati oúnjẹ alẹ".
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Tiếng Việt සිංහල Hausa Kurdî Kiswahili Português Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ ئۇيغۇرچە ไทย پښتو অসমীয়া دری Кыргызча or नेपाली Malagasy Kinyarwanda Română తెలుగు Lietuvių Oromoo മലയാളം Nederlands Soomaali Shqip Српски Українська Deutsch ಕನ್ನಡ Wolof Moore ქართული Azərbaycan Magyarالشرح
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pàṣẹ pẹlu riranti Ọlọhun nigba wiwọ inu ile ati ṣíwájú jijẹ oúnjẹ, ti o ba ranti Ọlọhun pẹlu sisọ pe: (Bismillah) nigba ti o ba wọ inu ile rẹ ati ìbẹ̀rẹ̀ jijẹ oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ fun awọn oluranlọwọ rẹ pé: Ko si ipin fun yin lati sun tabi lati jẹun alẹ ninu ile yii ti ẹni ti o ni i ti wa iṣọra kuro lọdọ yin pẹlu riranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-. Ṣugbọn ti ọkùnrin ba wọ ile rẹ ti ko ranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ tabi nigba jijẹ oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ fun awọn oluranlọwọ rẹ pe wọn ti ri ibusun ati oúnjẹ alẹ ninu ile yii.فوائد الحديث
Ṣíṣe iranti Ọlọhun nigba wiwọ inu ile ati oúnjẹ ni nnkan ti a fẹ, nitori pe Shaitan maa n gbe inu awọn ile, ti o si maa n jẹ oúnjẹ awọn ara ile ti wọn ko ba dárúkọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
Shaitan maa n ṣọ ọmọ Adam nibi iṣẹ rẹ ati ìwà rẹ ati nibi awọn àlámọ̀rí rẹ pata, ti o ba gbagbe lati ranti Ọlọhun, ọwọ rẹ maa tẹ erongba rẹ lọdọ rẹ.
Iranti maa n le Shaitan dànù.
Gbogbo èṣù kọọkan lo ni awọn ọmọlẹyin rẹ ati awọn ààyò rẹ ti wọn maa n dunnu pẹlu ọrọ rẹ ti wọn si n tẹle àṣẹ rẹ.