إعدادات العرض
Al-Lahumma Bā`id Baynī Wa Bayna Khaţāyāya Kamā Bā`adta Bayna Al-Mashriqi Wa Al-Maghribi
Al-Lahumma Bā`id Baynī Wa Bayna Khaţāyāya Kamā Bā`adta Bayna Al-Mashriqi Wa Al-Maghribi
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jẹ ẹni ti o ṣe pe, ti o ba ti kabara nibi irun, o maa n dakẹ fun igba díẹ̀ ṣíwájú ki o to ka Fatiha, mo wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun mo fi baba mi ati iya mi ṣe ìràpadà fún ọ, njẹ o ri idakẹ rẹ laaarin kikabara ati kika Fatiha, ki ni nnkan ti o maa n sọ? O sọ pe "mo maa n sọ pe: Al-Lahumma Bā`id Baynī Wa Bayna Khaţāyāya Kamā Bā`adta Bayna Al-Mashriqi Wa Al-Maghribi Al-Lahumma Naqqinī Min Khaţāyāya Kamā Yunaqqá Ath-Thawbu 'Illābyađu Mina Ad-Danasi Al-Lahumma Aghsilnī Min Khaţāyāya Bith-Thalji Wa Al-Mā'i Wa Al-Barad".
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Tiếng Việt ئۇيغۇرچە Hausa Português Kurdî Kiswahili සිංහල دری অসমীয়া ไทย አማርኛ Svenska Кыргызча ગુજરાતી नेपाली Oromoo മലയാളം Română Nederlands Soomaali پښتو తెలుగు Kinyarwanda ಕನ್ನಡ Malagasyالشرح
Ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ti kabara, o maa n dakẹ ni idakẹ díẹ̀ ṣíwájú ki o to ka Fatiha, o maa n bẹ̀rẹ̀ irun rẹ nibẹ pẹlu awọn adura kan, ninu eyi ti o wa ninu awọn adura yii ni ọrọ rẹ pé: "Al-Lahumma Bā`id Baynī Wa Bayna Khaţāyāya Kamā Bā`adta Bayna Al-Mashriqi Wa Al-Maghribi Al-Lahumma Naqqinī Min Khaţāyāya Kamā Yunaqqá Ath-Thawbu 'Illābyađu Mina Ad-Danasi Al-Lahumma Aghsilnī Min Khaţāyāya Bith-Thalji Wa Al-Mā'i Wa Al-Barad", O maa n bẹ Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- lati gbe awọn àṣìṣe jìnnà si oun ki oun ma ko si i, ni igbejinna kan ti ipadepọ ko lee ṣẹlẹ pẹlu rẹ, gẹgẹ bi ko ṣe le si ìpàdépọ̀ laaarin ibuyọ oorun ati ibuwọ oorun láéláé, ti oun ba wa ko si i, ki O fọ oun mọ kuro nibẹ ki O mu u kúrò bi wọn ṣe maa n mu ìdọ̀tí kuro lara aṣọ funfun, pe ki O fọ oun mọ kuro nibi awọn àṣìṣe rẹ ki O bu tutu si eyi ti o n jo ti o si gbóná nibẹ, pẹlu awọn nǹkan ti n mọ́ nǹkan ti o tutu yìí; omi ati yinyin.فوائد الحديث
Kika adura ìṣírun ni jẹẹjẹ koda ki irun jẹ eyi ti a maa n ki soke.
Ojúkòkòrò awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- lori mimọ awọn isẹsi ojiṣẹ - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi awọn lílọ bibọ rẹ ati iwalojukan rẹ.
Awọn agbekalẹ miiran wa fun adura iṣirun, ati pe eyi ti o daa julọ ni pe ki ọmọniyan tọ ipasẹ awọn adura iṣirun ti o wa ti o si fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ki o si mu eyi wa ni ẹẹkan, ki o mu òmíràn wa nigba mii.
التصنيفات
Awọn iranti irun