Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi dámilójú pé oun yóò ṣọ́ nkan tí n bẹ láàrín eegun ẹnu rẹ méjèèjì àti nkan tí n bẹ láàrín ẹsẹ̀ rẹ méjèèjì, èmi yóò fi dá a lójú pé yoo wọ Alujanna

Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi dámilójú pé oun yóò ṣọ́ nkan tí n bẹ láàrín eegun ẹnu rẹ méjèèjì àti nkan tí n bẹ láàrín ẹsẹ̀ rẹ méjèèjì, èmi yóò fi dá a lójú pé yoo wọ Alujanna

Lati ọdọ Sahl ọmọ Sahd - ki Ọlọhun yọnu si i - ó gba a wa lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pé ó sọ pé: "Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi dámilójú pé oun yóò ṣọ́ nkan tí n bẹ láàrín eegun ẹnu rẹ méjèèjì àti nkan tí n bẹ láàrín ẹsẹ̀ rẹ méjèèjì, èmi yóò fi dá a lójú pé yoo wọ Alujanna".

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọrọ nipa awọn nkan meji tó ṣe pé tí Musulumi bá dúnní mọ́ wọn, dajudaju yóò wọ Alujanna. Ikinni: Ṣíṣọ́ ẹnu kuro nibi sísọ nkan tí ó maa fa ibinu Ọlọhun Ọba, Èkejì: Ṣíṣọ́ abẹ́ kuro nibi ìṣekúṣe; nítorí pé awọn oríkèé ara meji wọnyi, ẹ̀ṣẹ̀ máa n waye latara wọn lọpọlọpọ ìgbà.

فوائد الحديث

Ṣíṣọ́ ẹnu ati abẹ́ jẹ́ ọ̀nà lati wọ inu Alujanna.

Wọ́n dá ẹnu ati abẹ́ ṣà lẹ́ṣà; nitori pe awọn mejeeji ni orisun aluba ati adanwo tí ó tobi julọ fún eniyan ni aye ati ọrun.

التصنيفات

Awọn iroyin alujanna