Ẹ jẹ kín fún yín ní ìró nipa awọn ẹni Alujanna? gbogbo ọlẹ ti ko lágbára rara, ti o ba búra iroro nkan síwaju Ọlọhun, Ọlọhun yóò sọ ọ di daada, ẹ jẹ kí nfun yin ni iro nipa awọn ẹni iná: gbogbo ẹni ti o le koko, ti nrin tanlu tanlu, oni moto moto

Ẹ jẹ kín fún yín ní ìró nipa awọn ẹni Alujanna? gbogbo ọlẹ ti ko lágbára rara, ti o ba búra iroro nkan síwaju Ọlọhun, Ọlọhun yóò sọ ọ di daada, ẹ jẹ kí nfun yin ni iro nipa awọn ẹni iná: gbogbo ẹni ti o le koko, ti nrin tanlu tanlu, oni moto moto

Lati ọdọ Haarithah ọmọ Wahbi Al-Khuzaa'iyy - ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - o sọ pe: mo gbọ Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - tí ń sọ bayi pe: "Ẹ jẹ kín fún yín ní ìró nipa awọn ẹni Alujanna? gbogbo ọlẹ ti ko lágbára rara, ti o ba búra iroro nkan síwaju Ọlọhun, Ọlọhun yóò sọ ọ di daada, ẹ jẹ kí nfun yin ni iro nipa awọn ẹni iná: gbogbo ẹni ti o le koko, ti nrin tanlu tanlu, oni moto moto".

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa niro apakan awọn iroyin awọn ẹni Alujanna (ọgbà idẹra) ati awọn ẹni ina. Awọn ti wọn pọ̀jù nínú ẹni Alujanna awọn ni: "gbogbo ọlẹ ti kò lágbára rara" itumọ rẹ nipe: ẹni tí o ntẹriba ti o si njirẹbẹ fún Ọlọhun ti o ga jùlọ, ti o rẹ raa rẹ fun Un, debiipe apakan awọn eniyan wọn npe e ni ọlẹ, wọn nyẹpẹrẹ rẹ̀, ẹni ti o yẹpẹrẹ araa rẹ̀ fun Ọlọhun yii, ti o ba fi Allah (Ọlọhun) bura ni enití n rokan si oore Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, Allah yoo sọ di daada, yoo si sọ ohun ti o bura le lori di ootọ, yoo si da lohun ohun ti o beere ati adua rẹ. Awọn ti wọn pọju ninu awọn ẹni iná ni gbogbo "oni iwa to le koko" ohun ni onibinu, ọlọkan líle koko, alajangbila, tabi oni iwa ibajẹ (alaburu) ti kii tẹriba fún daada, "onigirimọkai" ohun ni oni moto moto, Alajẹju (okuonjẹ), ẹni tori gbàngbà, ti nrin irin tanku taloku (irin akọ) oniwa buruku, "oni moto moto" pẹlu aigba ododo wọle, ati ifoju yẹpẹrẹ wo awọn elomiran.

فوائد الحديث

Iseni ni ojúkòkòrò lati gba iroyin pẹlu iroyin awọn ẹni Alujanna (ile-idẹra), ati isọni lara kuro nibi awọn iroyin awọn ẹni iná.

Ọlọhun Ọba ti O tobi julọ ni itẹriba fún tọ́sí, ati itẹriba fún àṣẹ àti máṣee Rẹ ati ki a sì gbafa fún awọn mejeeji, bẹẹ ni itẹriba wa fún àwọn ẹdá pẹlu ki a máṣe ṣe girimọkai (mọto moto) sí wọn.

Ibn Hajar sọ pe: ohun ti wọ́n gba lero nipe ọpọlọpọ awọn ẹni Alujanna (ile - idẹra) ni awọn wọnyii, bẹẹ naa ni ọpọlọpọ awọn eni iná ni awọn ipin keji ti wọn sọ, kii ṣe èróngbà wọn ni pe gbogbo awọn ẹni aaye mejeeji patapata ni awọn wọnyii.

التصنيفات

Isẹmi ọjọ ìkẹyìn